ODI MEJI-WPS Office
ODI MEJI-WPS Office
ODI MEJI-WPS Office
1. Birikoto ni won n pile odo, gboro gboro ni won n pile awon, toba gboroke tan, a gbodo, a gbolo, a
gbodukeeke baba isaasun adifa fun akesan tin se igba ile oduuja ja, eleyi ti yio boloriire lomo, wonni ko
rubo, o gbebo o rubo, o gberu o teru, nje akesan n dade, aya re n daja, eyin ko mo pe oloriire ni n daja.
2. Koko aso gburu kan, igede ni igede, eyin eyin ni won n jijo Orisa si, adifa fun idi kunrin a bun fun idi
binrin won n sunkun pe awon ko bimo, wonni kiwon o rubo, won rubo, won setutu, igba idi di meji lawa
gbekun omo tuntun.
3. O deere, o rin re, o mo irin asiko rin lese meejeeji, asese ko oun oro le tan lo wole de gere bi omo
olohun bee lee somo olohun, irin asiko lo mo rin lese meejeeji, adifa fun ajoji gologbo nijo ton lo re
bawon tun otu Ife se, tani yoo bawa tun ile yo se, ajooji gologbo, ifa ni yio bawa tun ile yi se.
4. Idindikiridi Babalawo ori lo difa fun ori, ori n be logbere oun nikan soso girogiro, Apa wa apa wa bori
duro, gbogbo ara wa, won wa bori duro, kerekere, ori mi kasai deleni, kerekere.
5. Idi meejeeji lo toluware joko lori eni adifa fun onibode ajenbere wu, eleyi ti yio gboju oju kanna mo
jifa wa oke, onibode kii nawo ana, waraja ni hun o faye ifa sofe je, waaraja.
6. Bebe ihin kandin, bebe ohun kandin adifa fun idi kunrin a bun fun won nidi binrin, won sunkun pe
awon ko ti omo bi , ebo ni wonni ki won o se, won gbebo nibe won rubo, won gberu won teru, igba idi di
meji lawa bi igba omo.