Seraphim Hymn Book Part 2
Seraphim Hymn Book Part 2
Seraphim Hymn Book Part 2
i 11s 10s
Ẹmi l'Ọlọrun awọn to ba n sin,
L'ẹmi at'otọ ni ki wọn kunlẹ:
Iwọ ti n gb’arin awọn Kérúbù,
Jọ sunmọ wa, gba t'a ba sunmọ Ọ.
AMIN
iii
1. Emi y'o gbadura s'Ọba mi Edumare)
Baba ye ko wa gba mi o e )2ce
Ọkan soso ajanaku,
Wa pẹlu mi nile Rẹ o,
Emi Ọmọ Rẹ — N ke pe Ọ, Baba wa rere.
Wa sure fun wa ka to lọ
Awọn agan to wa nibi,
Jẹ ki wọn finu s'oyun,
Awọn t'o ti bimọ,
Jẹ ki wọn r'owo fi tọ wọn,
Awọn ti ko r'isẹ se,
Pese isẹ fun wọn,
Awọn t'ile n le,
Jẹ ki ile r'oju fun wọn;
Edumare dakun, dakun, dakun,
Baba Mimọ, Baba a de loni o!
Wa sure fun wa ka to lọ.
ASẸ, AMIN O! KO
SẸ
xi Ye - Oluwa a de ) 2ce
Awa de o lati yin Ọ fun Ọjọ oni.
Ye Oluwa a de,
Awa de o lati juba Edumare Ọba to da wa,
Ye - Oluwa a de,
Dariji wa o — Baba wa,
Ma jẹ ka r'ohun asise.
Ye — Oluwa a de,
Awa de o lati juba Mose Orimọlade,
Ye — Oluwa a de,
Awa de o — Baba wa,
Awa Ọmọ Rẹ de o,
A tun de, a wa gbe Ọ larugẹ;
Ma jẹ k'oju ti wa o,
Ye — Oluwa ade,
Awa de o lati juba Rẹ o,
K'ọjọ oni le yẹ wa,
B'ọmọde ba juba Baba rẹ — aye a yẹ,
Jẹ k'ọjọ oni le yẹ wa o,
Edumare atobiju Baba.
.................INTERLUDE......................
xviii
1. Jesu, wa sarin wa,
L'agbar'Ajinde;
Jẹ k'isin wa nihin
Jẹ isin ọwọ.
3. Bi a ti n yara lọ,
Lọna ajo wa;
K'a ma sọna f'ọrọ,
T'o j'ayeraye. AMIN
xix
1. Baba, Baba, awa wolẹ niwaju Rẹ,
Baba, Baba, tan'mọlẹ Rẹ si wa,
Baba, Baba, oungbẹ Rẹ n gbẹ ọkan wa
Ẹmi ọrun sọkalẹ sarin wa.
Egbe: Fun wa l'agbara
At'ayọ n'nu ẹmi wa
Ka le dabi awọn t'ase logo
Ti n fi harpu wura yin i niwaju Rẹ,
Pẹlu Stephen ni aya Abraham.
xxi
Olu Ọrun awa de )
Ba ti juba fun Ọ o, )2ce
Ẹmi Ọrun jọwọ — Wa gbọ ti wa, )
.....................INTERLUDE..........................
Bi a ba jẹkọ, a darij'ewe,
Bi a ba j'ẹran a dari j'eegun o, Ọlọrun wa,
Olu idariji —dariji wa o. ASẸ
ASẸ
xxiii Awa ẹlẹsẹ de o — awa juba Baba ) 2ce
Bẹlẹjọ ba m'ẹjọ rẹ l'ẹbi,
Ko ni pẹ ni kunlẹ,
Awa jẹwọ ẹsẹ wa Baba — da wa lare,
Awa sa ti sẹ o,
Baba dakun ka wa yẹ loni i .
..........................INTERLUDE.........................
ASẸ
xxvi Ọlọrun Mose awa wolẹ — Eledumare,
Atobiju wa sure fun wa, (2ce)
Iwọ l'ọba ajikẹ )
Iwọ l'ọba aji pe o, ) 2ce
Arinurode Olumọran Ọkan ẹda,
A ko gbogb'ẹbẹ wa o - siwaju Rẹ.
..................INTERLUDE............. ..........
xxvii Ni kutukutu a de o — a de o,
Aji pọn omi kutukutu owurọ,
Ki pọn omi riru,
A wa kanlẹkun — a tẹwọ adura,
Baba jẹ ko yẹ wa.
........................INTERLUDE.........................
xxix
A t'ẹwọ adura — a t'ẹwọ adura,
Nile Ọlọrun — Awa t'ẹwọ adura,
Jẹwọ ẹsẹ rẹ o — Jẹwọ ẹsẹ rẹ o,
Ofin Ọlọrun ni kawa jẹwọ ẹsẹ wa,
A wolẹ adura — A wolẹ adura,
Nile Ọlọrun — awa wolẹ adura.
xxx
Ẹlẹru niyin awa de lorukọ Jesu )
Ọlọrun Séráfù awa wolẹ, ) 2ce
A ba buru, a tẹriba,
Awa gboju wa soke si Ọ fun aanu,
L'ọjọ oni o,
Gbogbo ẹsẹ ta ti da si Ọ,
Dariji wa Baba.
.......................INTERLUDE.....................
xxxiii
Dari ẹsẹ ji wa, )
Ọlọrun o — Ọlọrun wa )
Dari ẹsẹ ji wa, ) 2ce
Atobiju Ọlọrun wa, )
EGBE: Baba-Baba,
Jọwọ wa gbadura wa — Baba
xxxiv
Baba dariji wa o, ) 2ce
Awa ẹlẹsẹ abara m'ore jẹ,
Baba dariji wa o,
Ni ti mimọ a ko mọ, )
Ni ti yiyege a ko ye'ge )2ce
Bi a ba ni ka s'ami ẹsẹ,
Ko s'ẹni to le duro ninu wa—
Baba Ọrun - Jọwọ dariji wa o.
..............................INTERLUDE.........................
Ya wa si mimọ ) 2ce
Jẹ ka le wulo fun isẹ Rẹ,
Ya wa si mimọ,
Ogun aye — Ogun Esu, ) 2ce
Ma jẹ ko de wa lọna,
Ninu ara — Ninu ẹmi,
Ma jẹ k'adura wa ni 'de na,
Ya wa si mimọ.
ASẸ
SOLO: Jẹ ki oni yẹ wa o,
Ọlọjọ oni a' mbẹ Ọ,
FULL: Amin Amin ko sẹ Baba un un,
SOLO: K'aye wa dun ko l'oyin,
Ọlọjọ oni a mbẹ Ọ,
FULL: Amin ko sẹ Baba un un,
SOLO: K'aboyun bi tibi tire,
K'awọn agan d'ọlọmọ,
FULL: Amin — Amin ko sẹ Baba un un,
Buruburu la wa ba,
Lati gb'ohun wa soke si Ọ, ) 2ce
Messiah,
Ogo ni fun Ọ o — lyin fun Ọ loni,
Eledua ye sọkalẹ — Wa ba wa pe.
xxxvi
Edumare a ke pe Ọ o l'ọjọ oni )
Baba — wa gbọ igbe awa, ) 2ce
A ke pe Ọ l'ọdun esi — o da wa lohun,
Bekolo ba ju'ba ilẹ - ilẹ a lanu fun;
Iba Rẹ l'ọjọ oni o – a juba fun Ọ o,
.........................INTERLUDE.........................
.........................INTERLUDE.........................
xxxvii
1. Gba mi Baba gba mi dakun ye, )
Gba mi Baba gba mi dakun, ) 2ce
Ọgbagba ti n gba gbogbo ẹlẹsẹ, )2ce
Iwọ nikan sa ni mo d'ẹsẹ si Baba,
Gba mi Baba gba mi dakun ye,
Gba mi Baba gba mi dakun.
xxxviii
Tọwọtọwọ la wolẹ f'Ọlọrun Ọrun,
A ti mọ dajudaju pe,
B'ekolo ba juba ilẹ — ilẹ a lanu,
B'ọmọde juba Baba Rẹ a roko dalẹ,
Ọlọrun ifẹ a juba Rẹ o — Ki'ba sẹ,
.........................INTERLUDE......................
ASẸ
xl
(1) Baba a tun pade l'orukọ Jesu,
A si wa tẹriba l'abẹ ẹsẹ Rẹ,
A tun wa gb'ohun wa soke si Ọ,
Lati wa aanu lati kọrin iyin.
EGBE: O se a ko yẹ fun ifẹ nla Rẹ,
A sako kuro l'ọdọ Rẹ pọ ju,
Sugbọn kikan kikan ni o si n pe,
Njẹ a de a pada wa'le Baba.
EGBE: O se a ko yẹ...........e.t.c.
ASẸ
xli
Awa wolẹ Baba, )
Ijọ Séráfù de loni o ) 2ce
Ọba onibu ọrẹ,
Tiwa lẹyin lati Sioni wa,
Eledumare ran wa lọwọ,
Gb'ẹbọ sisun wa loni o,
Mu gbogbo ibere wa sẹ,
..........................INTERLUDE..........................
xlii
Baba Mimọ jọwọ a de o, )
Ninu Ijọ Rẹ - Baba, ) 2ce
Olugbala sunmọ wa — Ẹlẹru niyin o, )
Olugbala sunmọ wa — Ẹlẹru niyin o,
Olugbala sunmọ wa — Ẹlẹru niyin o.
Fun wa lowo si fun wa lọmọ o,
Ninu Ijọ Rẹ o Baba,
Olugbala gbohun wa Ẹlẹru niyin o.
Fun wa lọgbọn si fun wa loye o,
Ninu Ijọ Rẹ o - Baba,
Olugbala gbohun wa — Ẹlẹru niyin o,
Olugbala gbohun wa — Ẹlẹru niyin o,
Olugbala gbohun wa — Ẹlẹru niyin o.
ASẸ
xliii
Baba - Awa ọmọ Rẹ wolẹ bi t'esi, )
Messiah o gbani Baba, )
B'ọmọde dupẹ oore ana,
A tun gba miran,
Awa s'ọpẹ o lọpọlọpọ,
Baba ọrun o se.
xliv
Gbogbo ẹsẹ ni ibaba, )
Gbogbo ẹsẹ ni ikọkọ, )
Eyi ta ti sẹ'si Ọ — Olu Ọrun o,
Atobiju dariji wa o.
.............................INTERLUDE...........................
.
Basọ ba di riri,
A o gbe falagbafọ
Bile ba dọti,
A o fọ ile wa.
Tirẹ l'aye at'ẹkun rẹ,
Baba wa mi si wa.
.............................INTERLUDE...........................
.
2
“Kọ mi ni iwa ati imọ rere.”
-Ps. 119:66
2. Ẹmi iriran,
Baba wa, etc.
3. Ẹmi igbohun,
Baba wa, etc.
4. Silẹkun, silẹkun
Baba wa, etc.
5. Ẹmi iwosan,
Baba wa, etc.
6. Ẹmi otitọ
Baba wa, etc.
7. Ẹmi igbala,
Baba wa, etc.
3
TANI n fẹ Alafia? Emi n fẹ
Alafia ni Jesu fifun mi,
Lori ara mi o, Alafia Jesu fi fun mi.
Lori Aya “ “ “ ”
Lori Ọkọ “ “ “ ”
Lori Ọmọ “ “ “ ”
Lori Ẹbi “ “ “ ”
Lori Isẹ “ “ “ ”
Ninu Ile “ “ “ ”
Ninu Ijọ “ “ “ ”
4 Oju ma mọ lode
Egbe: Baba k'O ko wa yọ lọwọ ewu.
Lọwọ Ewu Oso “ “ “
Lọwọ Ewu Ajẹ “ “ “
Lọwọ Ewu Motor “ “ “
Lọwọ Ewu Kẹkẹ “ “ “
Lọwọ Ewu Ọkọ “ “ “
Lọwọ Ewu Ọta-Ile “ “ “
Lọwọ Ewu Ọta Ode “ “ “
Lọwọ Ewu gbogbo “ “ “
8 Fun mi lagbara
Egbe: Adaba Mimọ sọkalẹ wa o, fun mi lagbara,
Fun mi n’isẹgun, etc.
Fun mi n'iwosan, etc.
Fun mi n'ibukun, etc.
Fun mi n'Ayọ, etc.
Fun mi l’agbara, etc.
9 Atẹwọ ni gbalaja
Egbe: Ma fi gb'ọmọ rere
10
Ẹni n wa rere a ri rere(2)
Ọrọ mi dayọ niwaju Oluwa,
Ẹni n wa rere a ri 're,
Emi n wa rere ma ri 're (2)
Ọrọ mi dayọ niwaju Oluwa,
Emi n wa rere ma ri 're.
11 Mo r'ẹbun mi gba
Egbe: Ẹbun mi ma fi se ire.
12 Kọle s'ori Apata (2)
Ilẹ iyanrin a ba 'yanrin lọ,
Kọle s'ori Apata,
Duro l'ori Apata (2)
Ile iyanrin a ba 'yanrin lọ,
Duro l'ori Apata.
14 Oluwomisan Oluwomisan
Olugbamila Olugbamila
15 Olùgbàlà, gbadua mi
Egbe: Mo yọ, mo dupẹ o,
Oluwosan gbadura mi,
Olusẹgun gbadura mi,
Olupese “
Olubukun “
Alabo “
Oluwoye “
Ọba Ifẹ “
Jesu Kristi “
16 Ere-Ere Igbagbọ;
Ẹni ba n sin Jesu a ma r'ere je o (2)
Egbe: To ba s'emi lo ba sin Jesu
Ma ma r'ere jẹ o
To ba se'wọ lo ba sin Jesu
To ba s'ẹyin lo ba sin Jesu,
To ba s'awa lo ba sin Jesu,
Ere-Ere Igbagbọ
Ẹni ba n sin Jesu a ma r'ere jẹ o.
19
1. Gbogbo Isẹ Oluwa, f'ibukun f'Oluwa
Orun ati osupa, ẹ f'ibukun f'Oluwa
Oke ati ile, ẹ f'ibukun f'Oluwa
K'ẹ yin kẹ si ma gbega titi lai.
21 Abọ re o Jesu,
A jisẹ t'O ran wa,
Abọ re o Jesu
23
1. Ma b'Oluwa sowo pọ (2)
N ko ni padanu,
Ma b'Oluwa sowo pọ,
Ma ba Jesu sowo pọ,
K'emi le r'ere jẹ
Ma ba Jesu sowo pọ,
Ma nawo mi f'Olùgbàlà.
27 Baba n gbe'nu mi
Ọmọ n gbe'nu mi
Ẹmi Mimọ ti sọkalẹ,
Baba n gbe'nu mi,
Ọmọ n gbe'nu mi.
Pa'na Esu, pa'na ẹsẹ, etc.
Ran mi lọwọ, ti mi lehin,
Ran sẹgun fun mi, Gbe mi nija, etc.
“ Mu isẹ kuro lara mi,
“ F'ọkan ile balẹ fun mi,
“ Tani mo ni layé lọrun, bi ko se Iwọ, et c.
“ Tan 'mọlẹ si okunkun mi, etc.
“ Gbe ibi kuro lori mi, etc.
“ Da mi si tile-tọna mi, etc.
“ Fire fun mi, fayọ fun mi,
“ Ma yọ mi kuro l'ẹgbẹ yi
Jẹ k'emi lẹsẹ aseye l'ẹgbẹ yi
Ẹmi Mimọ ti ba le mi.
9. Farao at'ogun rẹ
N lepa Israeli bo o,
Wọn sure wọ'nu okun.
Okun pupa subu lu wọn
Israeli ti rekoja o,
Anu Rẹ duro lailai
32 C.M.
Fun Baba, Ọmọ, at'Ẹmi,
Ọlọrun t'awa n sin:
L'ogo wa bi ti igbani,
Ati titi lailai.
33 D.C.M.
Ẹ mu ẹbọ iyin wa fun,
Ọlọrun Olore:
Ko to rara fun Ọba wa,
Bẹ l'awa le se mọ!
Ogo fun Ọ, Mẹtalọkan,
Ọlọrun ti a n sin,
Bi t'igbani, bẹ nisinyi,
Bẹni titi lai.
AMIN
34 S.M.
Si Baba, at'Ọmọ,
At'Ẹmi ibukun,
S'Ẹni Mẹtalọkan soso,
L'a n kọrin 'yin lailai
AMIN
35 D.S.M.
Iyin bi t'igbani,
Iyin bi t'isin yii,
Iyin titi ainipẹkun,
L'ẹjẹ wa f'Ọlọrun;
Ẹni t'ogun ọrun,
At' awọn mimọ n sin;
Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ ,
L'ogo wa fun lailai
AMIN
36 6. 8s.
Iyin at'ẹyẹ ailopin,
Fun Baba Olodumare,
Ogo f'Ọmọ, Olùgbàlà,
To ku fun irapada;
Iyin bakan na ni fun Ọ,
Olutunu Ayérayé.
AMIN
37
Yin Ọlọrun ni ogo,
Ẹ yin labẹ ọrun;
Ẹ yin, ọm' ogun ọrun,
Baba, Ọmọ, at'Ẹmi.
AMIN
38 6s. 7s.
Baba, Ọmọ, at' Ẹmi,
Ọlọrun Mẹtalọkan,
Jẹ k'a se 'fẹ Rẹ layé,
Bi ogun ọrun ti n se!
K'ẹda gbogbo f'iyin fun;
Ọba ọrun at'ayé.
AMIN
39 7s.
Baba, Orisun 'mọlẹ,
Ọlọgbọn at'Olore;
Ọmọ t'O sọkalẹ wa,
Ba wa gbe, Emmanuel;
Ẹmi Adaba ọrun,
Olutunu, Olufẹ:
Iwọ l'awa n yin wi pé,
Mimọ, Mimọ, Mimọ lai.
AMIN
40 8s. 7s.
Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ ,
Ọlọrun Mẹtalọkan;
Iyin, ẹyẹ fun Ọ titi,
Ayé ti ko nipẹkun.
AMIN
41 8.7.4.
Yin Baba t'O gunwa lọrun!
Yin Ọmọ Ayérayé;
Yin Ẹmi t'a fun wa lọfẹ;
Yin Mẹtalọkan Mimọ;
Halleluyah!
Ayé ti ko nipẹkun.
AMIN
42 10s
Iyin at'ogo gbogbo fun Baba,
At' Ọmọ, at'Ẹmi Mẹtalọkan;
Bakan na lana, loni, ati lai,
Ni Iwọ Ọlọrun Ayérayé.
AMIN
43 7s. 6s.
Baba, Ologo lailai,
Ọmọ, Ayérayé,
Ẹmi Asẹgun gbogbo;
Mẹtalọkan Mimọ.
Ọlọrun Igbala wa,
T'ayé at'ọrun mbọ,
K'iyin, ogo, at'ẹyẹ
Jẹ Tirẹ titi lai.
AMIN
44 6s. 4s
Ẹ f'iyin fun Baba,
At'Ọmọ, oun Ẹmi,
Mẹtalọkan,
Gẹgẹ b'Oun ti wa ri,
Bẹni y'o si ma ri;
K'ẹni gbogbo buyin,
Layé, lọrun.
AMIN
45 8s
Ogo, ọla, iyin, ipa,
Ni f'Ọdaguntan titi lai:
Jesu Kristi l'Oludande wa,
Halleluya, yin Oluwa.
AMIN
46 C.M.
Emi gbagbọ, em'o gbagbọ
Pe, Jesu ku fun mi,
O t'ejẹ lor' agbelebu,
Lati yọ mi n n'ẹsẹ.
AMIN
47 S.M.
Baba, a f'ara wa,
S'isọ Rẹ l'alẹ yi;
Dabobo wa, k' O pa wa mọ,
Tit' ilẹ o fi mọ. AMIN
PSALMU 24
1. Ti Olúwa ni ilẹ ati ẹkun rẹ: ayé ati awọn ti o tẹdo sinu rẹ.
2. Nitori ti o fi idi rẹ sọlẹ lori okun, o si gbe e kalẹ lori awọn isan-omi.
3. Ta ni yio gun ori oke Olúwa lọ? Tabi tani yio duro ni ibi mimọ rẹ?
4. Ẹni ti o ni ọwọ mimọ, ati aya funfun: ẹni ti ko gbe ọkan rẹ soke si asan, ti ko
si bura ẹtan.
5. Oun ni yio ri ibukun gba lọwọ Olúwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun Igbala rẹ
6. Eyi ni iran awọn ti n se aferi rẹ, ti n se afẹri oju rẹ, Ọlọrun Jakobu.
7. Ẹ gbe ori yin soke, ẹyin ẹnu-ọna; ki a si gbe yin soke, ẹyin ilẹkun ayérayé: Ọba
Ogo yio si wọ inu ile lọ.
8. Ta ni Ọba ogo yi? Olúwa ti o le, ti o si lagbara, Olúwa ti o lagbara ni ogun.
9. Ẹ gbe ori yin soke, ẹyin ẹnu-ọna; ki ẹ gbe wọn soke, ẹyin ilẹkun ayérayé: Ọba
ogo yio si wọ inu ile lọ.
10. Ta ni Ọba Ogo yi? Olúwa awọn ọmọ-ogun; oun na ni Ọba ogo.
PSALMU 32
1. Ibukun ni fun ẹni ti a dari irekọja rẹ ji, ti a si bo ẹsẹ rẹ mọlẹ
2. Ibukun ni fun ọkunrin na ẹni ti Olúwa ko ka ẹsẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹni ti
ẹtan ko si.
3. Nigba ti mo dakẹ, egungun mi di gbigbo, nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ.
4. Nitori ni ọsan ati ni oru, ọwọ rẹ wuwo si mi lara emi ara mi si dabi ọda-ẹrun
5. Emi jẹwọ ẹsẹ mi fun ọ, ati ẹsẹ mi ni emi ko si fi pamọ, Emi wi pé, emi o jẹwọ
irekọja mi fun Olúwa; iwọ si dari ẹbi ẹsẹ mi ji.
6. Nitori idi eyi ni olukuluku ẹni iwa-bi-Ọlọrun; yio ma gbadura si o ni igba ti a
le ri ọ: nitotọ ninu isan-omi nla, wọn ki yio sunmọ ọdọ rẹ.
7. Iwọ, ni ibi ipamọ mi: iwọ o pa mi mọ kuro ninu isẹ: iwọ o fi orin igbala yi mi
ka kiri.
8. Emi o fi ẹsẹ rẹ le ọna, emi o si kọ ọ ni ọna ti iwọ o rin: emi o ma fi oju mi tọ
ọ
9. Ki ẹyin ki o mase dabi ẹsin tabi ibaka, ti ko ni iye ninu: ẹnu ẹni ti a ko le se
aifi ijanu bọ, ki wọn ki o ma ba sunmọ ọ.
10. Ọpọ ikanu ni yio wa fun eniyan buburu: sugbọn ẹni ti o ba gbẹkẹle Olúwa, anu
ni yio yi i ka kari.
11. Ki inu yin ki o dun ni ti Olúwa, ki ẹ si ma yọ, ẹyin olododo; ki ẹ si ma kọrin
fun ayọ, gbogbo ẹyin ti ọkan yin duro sinsin.
PSALMU 51
1. Ọlọrun, saanu fun mi, gẹgẹ bi iseun ifẹ rẹ: gẹgẹ bi ọpọ anu rẹ, nu irekọja mi
nu kuro.
2. Wẹ mi ni awẹmọ kuro ninu aisedede mi, ki o si wẹ mi nu kuro ninu ẹsẹ mi.
3. Nitori ti mo jẹwọ irekọja mi: nigba gbogbo ni ẹsẹ mi si mbẹ niwaju mi:
4. Iwọ, iwọ nikansoso ni mo sẹ si, ti mo se buburu yi niwaju rẹ: ki a le da ọ
lare nigba ti iwọ ba n sọrọ, ki ara rẹ ki o le mọ, nigba ti iwọ ba n se idajọ.
5. Kiyesi, ninu aisedede ni a gbe bi mi: ati ninu ẹsẹ ni iya mi si loyun mi.
6. Kiyesi, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ikọkọ ni iwọ o mu mi mọ ọgbọn.
7. Fi ewe hisopu fọ mi, emi o si mọ: wẹ mi, emi o si fun ju ẹgbọn owu lọ.
8. Mu mi gbọ ayọ ati inu didun, ki awọn egungun ti iwọ ti sẹ ki o le ma yọ.
9. Pa oju rẹ mọ kuro lara ẹsẹ mi, ki iwọ ki o si nu gbogbo aisedede mi nu kuro
10. Da aya titun sinu mi, Ọlọrun: ki o si tun ọkan didurosin-sin se sinu mi.
11. Mase sa mi ti kuro niwaju rẹ: ki o ma si se gba Ẹmi Mimọ rẹ lọwọ mi.
12. Mu ayọ igbala rẹ pada tọ mi wa; ki o si fi ẹmi omnira rẹ gbe mi duro.
13. Nigba na ni emi o ma kọ awọn olurekoja ni ọna rẹ: awọn ẹlẹsẹ yio si ma yi pada
si ọ.
14. Ọlọrun, gba mi lọwọ ẹbi ẹjẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi, ahọn mi yio si ma kọrin
ododo rẹ kikan
15. Olúwa, iwọ si mi ni ete: ẹnu mi yio si ma fi iyin rẹ han.
16. Nitori iwọ ko fẹ ẹbo, ti emi iba ru u: inu rẹ ko dun si ọrẹ ẹbọ sisun.
17. Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkan: irobinujẹ ati irora aya, Ọlọrun, oun ni iwọ ki
yio gan;
18. Se rere ni didun inu rẹ si Sioni: iwọ mọ odi Jerusalẹmu.
19. Nigba na ni inu rẹ yio dun si ẹbọ ododo: pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun ati ọtọtọ ọrẹ-ẹbọ
sisun: nigba na ni wọn o fi akọ-malu rubọ lori pẹpẹ rẹ.
PSALMU 99
1. Olúwa, jọba: jẹ ki awọn eniyan ki o wariri, o joko lori awọn Kérúbù; ki ayé ki o
ta gbọngbọn.
2. Olúwa to bi ni Sioni: o si ga ju gbogbo Orile-ede lọ
3. Ki wọn ki o yin orukọ rẹ ti o tobi, ti o si ni ẹru; mimọ ni oun.
4. Agbara Ọba fẹ idajọ pẹlu: iwọ fi idi aisegbe mulẹ; iwọ n se idajọ ati ododo ni
Jakọbu.
5. Ẹ gbe Olúwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si foribalẹ nibi apoti itisẹ rẹ: mimọ ni oun.
6. Mose ati Aaroni ninu awọn alufa rẹ, ati Samueli ninu awọn ti n pe orukọ rẹ: wọn
ke pe Olúwa, o si da wọn lohun.
7. O ba wọn sọrọ ninu ọwọn awọsanma: wọn pa ẹri rẹ mọ ati ilana ti o fifun wọn.
8. Iwọ da wọn lohun, Olúwa Ọlọrun wa: iwọ ni Ọlọrun ti o dariji wọn, bi o tilẹ se
pe iwọ san ẹsan isẹ wọn.
9. Ẹ gbe Olúwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si ma sin nibi oke mimọ rẹ; nitori mimọ ni Olúwa
Ọlọrun wa.
PSALMU 116
1. Emi fẹ Olúwa nitori ti o gbọ ohun mi ati ẹbẹ mi.
2. Nitori o de ẹti re si mi, nitori naa ni emi o ma ke pe e niwọn ọjọ mi.
3. Ikanu iku yi mi ka, ati irora isa-oku di mi mu; mo ri iyọnu ati ikanu.
4. Nigba naa ni mo ke pe orukọ Olúwa; Olúwa emi bẹ ọ gba ọkan mi.
5. Olore-ọfẹ ni Olúwa, ati olododo; nitotọ, alanu ni Ọlọrun wa.
6. Olúwa pa awọn alaimọkan mọ; a rẹ mi silẹ tan, o si gba mi.
7. Pada si ibi isinmi rẹ, iwọ ọkan mi; nitori ti Olúwa se ọpọlọpọ fun ọ.
8. Nitori ti iwọ ti gba ọkan mi lọwọ iku, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ
isubu.
9. Emi o ma rin niwaju Olúwa ni ilẹ alaye.
10. Emi gbagbọ, nitori na ni emi se sọ; mo ri ipọnju gidigidi.
11. Mo wi ni iyara mi pe: Eke ni gbogbo eniyan.
12. Ki ni emi o san fun Olúwa nitori gbogbo ore rẹ si mi?
13. Emi o mu ago igbala, emi o si ma ke pe orukọ Olúwa.
14. Emi o san ileri ifẹ mi fun Olúwa, nitoto ni oju gbogbo awọn eniyan rẹ.
15. Iyebiye ni iku awọn eniyan mimọ rẹ ni oju Olúwa.
16. Olúwa, nitoto iransẹ rẹ ni emi; iransẹ rẹ ni emi, ati ọmọ iransẹ-binrin rẹ: iwọ
ti tu ide mi.
17. Emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o si ma ke pe orukọ Olúwa.
18.Emi o san ileri ifẹ mi fun Olúwa, nitotọ ni oju gbogbo awọn eniyan rẹ.
19. Ninu agbala ile Olúwa, ni arin rẹ, iwọ Jerusalemu. Ẹ yin Olúwa.
PSALMU 128
1. Ibukun ni fun gbogbo ẹni ti o bẹru Olúwa: ti o si n rin ni ọna rẹ.
2. Nitori ti iwọ o jẹ isẹ ọwọ rẹ: ibukun ni fun ọ: yio si dara fun ọ.
3. Obinrin rẹ yio dabi ajara rere eleso pupọ ninu ile rẹ: awọn ọmọ rẹ yoo dabi igi
olifi yi tabili rẹ ka.
4. Kiyesi pe, bẹẹ ni a o busi fun ọkunrin na, ti o bẹru Olúwa.
5. Ki Olúwa ki o busi fun ọ lati Sioni wa, ki iwọ ki o si ma ri ire Jerusalemu ni
ọjọ ayé rẹ gbogbo.
6. Bẹni ki iwọ ki o si ma ri ati ọmọ-de-ọmọ rẹ; ati alafia lara Israeli.
PSALMU 130
1. Lati inu ibu wa ni emi ke pe ọ, Olúwa,
2. Olúwa, gbohun mi: jẹ ki eti rẹ ki o tẹ silẹ si ohun ẹbẹ mi.
3. Olúwa, iba se pe iwọ n sami ẹsẹ, Olúwa, tani yoo duro?
4. Nitori idariji wa lọdọ rẹ, ki a le ma bẹru rẹ.
5. Emi duro de Olúwa, ọkan mi duro, ati ninu ọrọ rẹ ni emi n se ireti.
6. Ọkan mi duro de Olúwa, ju awọn ti n sọna owurọ lọ, ani ju awọn ti n sọna owurọ
lọ.
7. Israeli, iwọ ni ireti lọdọ Olúwa: nitori pe lọdọ Olúwa ni anu wa, ati lọdọ rẹ
ni ọpọlọpọ idande wa.
8. Oun o si da Israeli nide kuro ninu ẹsẹ rẹ gbogbo.
PSALMU 133
1. Kiyesi, o ti dara o si ti dun to fun awọn ara lati ma jumọ gbe ni irẹpọ;
2. O dabi ororo iyebiye ni ori, ti o san de irugbọn, ani irugbọn Aaroni: ti o si
san si eti asọ rẹ:
3. Bi iri Hermoni ti o se sori Oke Sioni: nitori nibẹ ni Olúwa gbe pasẹ ibukun, ani
iye lailai.
ADURA OLÚWA
Baba wa ti mbẹ ni ọrun, ki a bọwọ fun orukọ rẹ. Ki Ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni
ki a se ni ayé, bi wọn ti n se ni ọrun. Fun wa ni Ounjẹ Oojọ wa loni. Dari ẹsẹ wa
ji wa, bi a ti n dari ẹsẹ ji awọn ti o sẹ wa. Ma fa wa sinu idẹwo: Sugbọn gba wa
lọwọ bilisi: Nitori ijọba ni tirẹ, agbara ni tirẹ, ogo ni tirẹ, lailai. AMIN
IGBAGBỌ
Mo gba Ọlọrun Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda ọrun oun ayé:
Mo gba Jesu Kristi gbọ, ọmọ rẹ kansoso Olúwa wa, ẹni ti a fi Ẹmi Mimọ loyun,
ẹni ti a bi ninu Maria Wundia, ẹni ti o jiya lọwọ Pontiu Pilatu, ẹni ti a kan mọ
agbelebu, ẹni ti o ku, ti a si sin, O sọkalẹ rẹ ipo oku; Ni ijọ kẹta o tun jinde
kuro ninu oku, O re oke ọrun, O si joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba Olodumare: Nibẹ ni
yio ti wa se idajọ aye oun oku.
Mo gba Ẹmi Mimọ gbọ, Ijọ Mimọ Ọlọrun; Idapọ awọn eniyan Mimọ;
Idariji ẹsẹ, Ajinde ara ni isa oku, Ati iye ti ko nipẹkun.
AMIN
PART II
FUN ỌJỌ GOOD FRIDAY ATI AJINDE
Mo gba Ọlọrun kan Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda ọrun oun ayé, ati ohun gbogbo ti
a n ri ati eyi ti a ko ri.
Mo gba Olúwa kan Jesu Kristi gbọ, ọmọ bibi nikansoso ti Ọlọrun, Ti a bi lati
ọdọ Baba rẹ saaju ayé gbogbo, Ọlọrun lati inu Ọlọrun, Imọlẹ lati inu Imọlẹ, Ọlọrun
tikararẹ lati inu Ọlọrun tikararẹ, ẹni ti a bi ti a ko da, ti ise ara kan naa pẹlu
Baba; Lati ọwọ ẹni ti a ti da ohun gbogbo, Ẹni, nitori awa eniyan, ati nitori
igbala wa, ti o ti ọrun wa si ile, ẹni ti o si mu awọ ara nipa Ẹmi Mimọ lara Maria
Wundia, O si di eniyan, a si kan a mọ agbelebu pẹlu nitori wa lọwọ Pontiu Pilatu. O
jiya a si sin in. Ni ijọ kẹta o si tun jinde gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun. O si lọ soke
ọrun, O si joko lọwọ ọtun Baba. Yio si tun pada wa ti oun ti Ogo, lati se idajọ aye
ati oku: Ijọba ẹni ti ki yio nipẹkun.
Mo si gba Ẹmi Mimọ gbọ, Olúwa ati Olufunni ni iye, ẹni ti n ti ọdọ Baba ati
Ọmọ wa, pẹlu Baba ati Ọmọ ẹni ti a n sin ti a sin yin logo pọ, ẹni ti o ti ẹnu awọn
Woli sọrọ. Mo si gba Ijọ Mimọ Eniyan Ọlọrun kan ati ti awọn Aposteli gbọ. Mo jẹwọ
Baptismu kan fun imukuro ẹsẹ, emi si n reti Ajinde oku, ati iye ti mbọ wa. AMIN
IFIHAN 4
1. Lẹyin nkan wọnyi emi wo, si kiyesi i, ilẹkun kan si silẹ ni ọrun: ohun kini ti
mo gbọ bi ohun ipe ti mba mi sọrọ, ti o wi pé, Goke wa ihin, emi o si fi ohun ti
yio hu lẹhin-ọla han ọ.
2. Lojukan naa mo si wa ninu Ẹmi; si kiyesi, a tẹ itẹ kan ni ọrun, ẹnikan si
joko lori itẹ na.
3. Ẹni ti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo; osumare si ta yi itẹ na
ka, o dabi okuta smaragdu ni wiwo.
4. Yi itẹ naa ka si ni itẹ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ na mo ri awọn agba
mẹrinlelogun joko, ti a wọ ni asọ ala; ade wura si wa ni ori wọn.
5. Ati lati ibi itẹ naa ni manamana ati ara ati ohun ti jade wa: fitila ina meje si
n tan nibẹ niwaju itẹ na ti ise Ẹmi meje ti Ọlọrun
6. Ati niwaju itẹ na si ni okun bi digi, o dabi Kristali: ni arin itẹ na, ati yi
itẹ na ka, ni ẹda alaye mẹrin ti o kun fun oju niwaju ati lẹhin.
7. Ẹda kini si dabi kiniun, ẹda keji si dabi ọmọ malu, ẹda kẹta si ni oju bi ti
eniyan, ẹda kẹrin si dabi idi ti n fo.
8. Awọn ẹda alaye mẹrin na, ti olukuluku wọn ni iyẹ mẹfa, kun fun oju yika ati
ninu: wọn ko si sinmi ni ọsan ati ni oru, wi pé, Mimọ, Mimọ, Mimọ, Olúwa Ọlọrun
Olodumare, ti o ti wa, ti o si mbẹ, ti o si mbọ wa.
9. Nigba ti awọn ẹda alaye naa ba si fi ogo ati ọla ati ọpẹ fun ẹni ti o joko lori
itẹ, ti o mbẹ laye lai ati lailai.
10. Awọn agba mẹrinlelogun na a si wolẹ niwaju ẹni ti o joko lori itẹ, wọn a si
tẹriba fun ẹni ti mbẹ laye lai ati lailai, wọn a si fi ade wọn lelẹ niwaju itẹ naa
wi pé,
11. Olúwa, iwọ ni o yẹ lati gba ogo ati ọla ati agbara: nitori pe iwọ ni o da ohun
gbogbo, ati nitori ifẹ inu re ni wọn fi wa ti a si da wọn.
ISAIAH 6
1. Ni ọdun ti Ussaiah Ọba ku, emi ri Olúwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara
soke, isẹti asọ igunwa rẹ kun tempili.
2. Awọn Séráfù duro loke rẹ; ọkọọkan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bo oju rẹ, o si fi
meji bo ẹsẹ rẹ, o si fi meji fo.
3. Ikini si ke si ekeji pe, Mimọ, mimọ, mimọ, ni Olúwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo ayé
kun fun ogo rẹ.
4. Awọn opo ilẹkun si mi nipa ohun ẹni ti o ke, ile naa si kun fun efin.
5. Nigba naa ni mo wi pé, Egbe ni fun mi, nitori mo gbe, nitori ti mo jẹ ẹni-alaimọ
ete, mo si wa larin awọn eniyan alaimọ ete, nitori ti oju mi ti ri Ọba, Olúwa awọn
ọmọ-ogun.
6. Nigba naa ni ọkan ninu awọn Séráfù fo wa sọdọ mi, o ni ẹsẹ-ina ni ọwọ rẹ, ti o
ti fi ẹmu mu lati ori pẹpẹ wa.
7. O si fi kan mi ni ẹnu, o si wi pé, kiyesi i, eyi ti kan ete rẹ, a mu aisedede
rẹ kuro, a si fo ẹsẹ rẹ nu.
8. Emi si gbọ ohun Olúwa pẹlu wi pé, Tani emi o ran; ati tani o si lọ fun wa? Nigba
na ni emi wi pé, emi ni; ran mi.
Nigba naa ni Alufa yoo bere lọwọ ẹni ti (awọn ẹni ti) a o baptist pe:-
Iwọ ha ko esu ati gbogbo ise rẹ silẹ, afẹ asan ati ogo ayé, pẹlu ojukokoro
ifẹ gbogbo, ati ifẹkufẹ ti ise ti ara; tobẹ ti iwọ ki yoo ma tọ wọn lẹhin, bẹni
wọn ki yoo ma se amọna rẹ?
Idahun: Mo kọ gbogbo wọn silẹ.
Alufa: Iwọ gba Ọlọrun Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda ọrun oun ayé? Iwọ gba
Jesu Kristi gbọ, Ọmọ bibi Rẹ nikansoso Olúwa wa? Ati pe nipa Ẹmi Mimọ ni a ti
loyun Rẹ; a bi i ninu Maria Wundia; o jiya lọwọ Pontiu Pilatu, a kan a mọ agbelebu,
O ku, a si sin in; o sọkalẹ re ipo oku, ati pẹlu pe ni ọjọ kẹta o tun jinde, o re
oke ọrun, o si joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba Olodumare: ati pe nibẹ ni yoo tun pada
wa ni opin ayé, lati se idajọ ààyè oun oku?
Iwọ si gba Ẹmi Mimọ gbọ: Ijọ mimọ Eniyan Ọlọrun; Idapọ awọn, Eniyan Mimọ;
Idariji ẹsẹ; Ajinde ara ni isa oku; ati iye ti ko nipẹkun lẹhin iku?
Idahun: Gbogbo eyi ni mo gbagbọ tọkantọkan.
Alufa: Iwọ ha fẹ ki a baptisi rẹ ninu igbagbọ yi?
Idahun: Ifẹ inu mi ni.
Alufa: Iwọ ha n fẹ tọkantọkan lati gba Kristi Olúwa bi Olùgbàlà rẹ, ki o
si gbẹkẹle Oun nikansoso fun igbala layé yii ati layé ti mbọ?
Idahun: Ifẹ inu mi ni.
Alufa: Iwọ o ha ma fi igbagbọ pa ifẹ ati ofin mimọ Ọlọrun mọ, ki iwọ ki
o si ma rin ninu wọn ni ọjọ ayé rẹ gbogbo?
Idahun: Emi o pa a mọ nipa iranlọwọ Ọlọrun.
Ẹ jẹ ki a gbadura.
Ẹ sọ eleyi ni orukọ
AWA gba eleyi sinu agbo Ijọ Kristi, awa si saa ni ami Agbelebu, apẹrẹ pe
lẹhin eyi ki yoo tiju ati jẹwọ igbagbọ Kristi ti a kan mọ agbelebu, ati lati ba
ẹsẹ, ayé, ati esu ja bi ọkunrin labẹ ọpagun rẹ; ati lati duro bi ọmọ-ogun Kristi
nitotọ ati bi ọmọ-ọdọ rẹ titi opin ẹmi rẹ. Amin.
IDAPO MIMỌ
A ki yoo gba ẹnikẹni si Idapọ Mimọ ni Ijọ tabi Ẹkun ti ki ise inu ẹni ti eyi
ti o wa, laijẹ pe o ko fi iwe Alagba Ijọ tabi Ẹkun rẹ fi ọwọ si han, ti o si fihan
pe ẹni kikun ninu Ijọ oun.
Nigba ti Idapọ Mimọ yoo ba tele Adura Owurọ lẹsẹ kan naa, Alagba le bẹrẹ Isin
Idapọ Mimọ lehin Ohun ti o tẹle Ẹkọ Kika Keji ninu Adura Owurọ.
Baba wa ti mbẹ ni mbẹ, Ki a bowo fun oruko rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni
ki a se ni ayé. Bi wọn ti n se ni mbẹ. Fun wa ni Ounjẹ oojọ wa loni. Dari ẹsẹ wa
ji wa. Bi a ti n dari ẹsẹ ji awọn ti o sẹ wa. Ma fa wa sinu idẹwo: sugbọn gba wa
lọwọ bilisi. Amin.
ADURA
ỌLỌRUN Olodumare, ẹni ti gbogbo ọkan wa sipaya fun, ẹni ti gbogbo ifẹ inu wa
di mimọ fun, ati ẹni ti ohun ikọkọ kan ko fi ara pamọ lọdọ rẹ; Fi imisi Ẹmi Mimọ
rẹ we iro inu wa nu, ki awa ki o le ma fe o ni afẹtan, ki a si le ma gbe Orukọ mimọ
rẹ ga bi o ti yẹ; nitori Kristi Olúwa wa. Amin.
A o ka Ofin Mẹwa wọnyii ni Isin Idapọ Mimọ ni Ọjọ Isinmi. Sugbọn bi Isin
Idapọ Mimọ ba ju ekan lo ni Ọjọ Isinmi, a o fi awọn ọrọ Olúwa wa wọnyii dipo wọn.
Alagba: Jesu Kristi Olúwa wa wi pé, Gbo Israeli, Olúwa Ọlọrun wa, Olúwa kan ni.
Ki iwọ ki o fi gbogbo aya rẹ, ati gbogbo ọkan rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ Ọlọrun
Olúwa rẹ. Eyi ni ekini ati ofin nla. Ekeji si dabi rẹ, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara
rẹ. Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati woli rọ mọ.
Idahun: Olúwa, saanu fun wa, ki o si gbogbo ofin rẹ wọnyii si wa ni ọkan, awa mbẹbẹ
lọdọ rẹ.
OFIN MẸWA
Alagba: Ọlọrun sọ gbogbo ọrọ wọnyii pe; Emi ni Olúwa Ọlọrun rẹ: Iwọ ko gbọdọ ni
Ọlọrun miran pẹlu mi.
Idahun: Olúwa, sàánú fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ ya erekere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ ni oke
ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ile, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni
isalẹ ilẹ. Iwọ ko gbọdọ tẹriba fun wọn, bẹni iwọ ko gbọdọ sin wọn; nitori Emi ni
Olúwa, Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owu ni ni, ti mbẹ ẹsẹ awọn baba wo lara awọn ọmọ, titi de
iran ẹkẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi, Emi a si ma fi anu han ẹgbẹgbẹrun
awọn ti o fẹ mi, ti wọn si n pa ofin mi mọ.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ pe orukọ Olúwa Ọlọrun rẹ lasan: nitori Olúwa ki yoo salai
debi fun awọn ti n pe oruko rẹ layé.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba : Ranti ọjọ Isinmi lati lo o ni mimọ. Ọjọ mẹfa ni iwọ o sisẹ, ti iwọ o
si se isẹ rẹ gbogbo; sugbọn ọjọ keje ni ọjọ Isinmi Olúwa Ọlọrun rẹ. Ninu rẹ iwọ ko
gbọdọ se isẹkisẹ kan, iwọ, tabi ọmọ rẹ okunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, tabi ọmọ-ọdọ
rẹ okunrin, tabi ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, tabi ohun ọsin rẹ, tabi alejo rẹ ti mbẹ ninu
odi rẹ. Nitori ni ọjọ mẹfa ni Olúwa da mbẹ oun ayé, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ
ninu wọn, o si sinmi ni ọjọ keje: nitori naa ni Olúwa se busi ọjọ keje, o si ya a
si mimọ.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Bọwọ fun baba oun iya rẹ: ki ọjọ rẹ ki o le pẹ ni ile ti Olúwa Ọlọrun
rẹ fifun ọ.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ paniyan.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ se pansaga
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ jale
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ.
Idahun: Olúwa, saanu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ sojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ ko gbọdọ sojukokoro si
aya ẹnikeji rẹ, tabi ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ-odo rẹ obinrin, tabi malu rẹ,
tabi kẹtẹkẹtẹ rẹ, tabi si ohunkohun ti ise ti ẹnikeji rẹ.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si kọ gbogbo ofin rẹ wọnyii si wa ni ọkan, awa
mbẹbẹ lọdọ rẹ.
Nigba naa ni Alagba o gba ọkan ninu awọn Adura meji yi fun Ọba, yoo si wi pé:
Ẹ JẸ KI A GBADURA
Tabi eyi,
OLODUMARE ati ayérayé Ọlọrun, ninu ọrọ mimọ rẹ ni a gbe kọ wa pe, ọkan awọn
Ọba mbẹ ni ikawọ ati akoso rẹ, pe Iwọ ni idari wọn ti o si ma itọ wọn nipa ọgbọn rẹ
gẹgẹ bi o ti yẹ; Awa n fi iparamọ bẹbẹ lọdọ rẹ lati dari ati lati se akoso ọkan
N- Ọba (Baalẹ,) Iransẹ rẹ, ni iro, ọrọ, ati ise rẹ gbogbo, ki o le ma tọju ọla ati
ogo rẹ, ki o si le ma humọ ati pa awọn eniyan rẹ mo ti a fi si isọ rẹ ni irọra,
alafia, ati ni iwa-bi-Ọlọrun: Fi eyi funni, Baba alaanu, nitori ti ọmọ rẹ ọwọn,
Jesu Kristi Olúwa wa. Amin
Nigba naa ni Alagba o gba Adura ti a yan fun ọjọ na.
Mo gba Ọlọrun kan Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda mbẹ oun ayé. Ati ohun gbogbo ti a
n ri ati eyi ti a ko ri.
Mo gba Olúwa kan Jesu Kristi gbọ, ọmọ bibi nikansoso ti Ọlọrun, Ti a bi lati
ọdọ Baba rẹ saaju ayé gbogbo, Ọlọrun lati inu Ọlọrun, Imọlẹ lati inu Imọlẹ, Ọlọrun
tikararẹ lati inu Ọlọrun tikararẹ, ẹni ti a bi ti a ko da, ti ise ara kan naa pẹlu
Baba; Lati ọwọ ẹni ti a ti da ohun gbogbo, Ẹni, nitori awa eniyan, ati nitori
igbala wa, ti o ti mbẹ wa si ile, ẹni ti o si mu awo ara nipa Ẹmi Mimọ lara Maria
Wundia. O si di eniyan, A si kan a mọ agbelebu pẹlu nitori wa lọwọ Pontiu Pilatu. O
jiya a si sin in, Ni ọjọ keta o si tun jinde gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun, O si lọ soke mbẹ,
O si joko lọwọ ọtun Baba. Yoo si tun pada wa ti oun ti ogo, lati se idajọ aye ati
oku; Ijọba ẹni ti ki yoo nipẹkun.
Mo si gba Ẹmi Mimọ gbọ, Olúwa ati Olufunni ni iye, ẹni ti n ti ọdọ Baba ati
Ọmọ wa, Pẹlu Baba ati Ọmọ ẹni ti a n sin ti a sin yin logo pọ, ẹni ti o ti ẹnu awọn
Woli sọrọ. Mo si gba Ijọ Katoliki kan ati awọn Aposteli gbọ, Mo jẹwọ Baptismu kan
fun imukuro ẹsẹ, Emi si n reti ajinde oku, Ati iye ayé ti mbọ wa. Amin.
Nigba naa ni a o bẹrẹ si gba ọrẹ Ijọ, Alagba yoo si ma ka ninu awọn ọrọ
Ọlọrun wọnyii. Nigba ti a ba gba ọrẹ tan, a o fi tọwọ-tọwọ gbe e tọ Alagba wa, ẹni
ti yoo gba adura yi, ti yoo si fi irẹlẹ gbe ọrẹ naa sori Tabili Mimọ.
ADURA
OLÚWA, masai gba ọrẹ awọn eniyan rẹ wọnyii, ki o si lo wọn fun ogo rẹ. dari
gbogbo aipe tabi abuku wa ji wa, ki o si fi ibukun rẹ fun awọn ti o mu awọn ọrẹ
atinuwa wọnyii wa fun ọ; nitori Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
OLODUMARE ati lai Ọlọrun Alaye, ẹni ti o ti ọwọ Aposteli rẹ mimọ ko wa lati
ma gbadura, lati ma bẹbẹ, ati lati ma dupẹ fun gbogbo eniyan; Awa n fi iparamọ bebe
lowo rẹ, ninu anu rẹ nla, ki iwọ ki o (gba ore anu ati ẹbun wa, ati ki o si) gba
adura wa wọnyii, ti awa n gba si Ọla-nla Iwa mimọ rẹ; awa mbẹbẹ lodo rẹ, ki iwọ ki
o ma mi ẹmi otitọ, isọkan, ati irepo, nigba gbogbo si gbogbo Ijọ mimọ rẹ: Ki iwọ
ki o si fi fun’ni, ki gbogbo awọn ti o jẹwọ Orukọ mimọ rẹ le ni ohun kan niti otitọ
ọrọ mimọ rẹ, ki wọn ki o si wa ni isọkan, ati ni ifẹ-bi-Ọlọrun. Awa si mbẹbẹ lọdọ
Rẹ lati to gbogbo orilẹ-ede ni ọna ododo ati alafia: ati lati dari gbogbo awọn Ọba
ati awọn Ijoye pe ki a le fi iwa-bi-Ọlọrun ati iwa pẹlẹ se akoso awọn eniyan Rẹ
labẹ oye wọn; ki o si fifun Ọba, awọn Igbimọ rẹ, ati gbogbo awọn ti a fi si ibi ọla
labẹ rẹ, ki wọn ki o le ma fi otitọ, aisoju saaju dajọ aisegbe, lati se iwa-buburu
ati iwa-ẹsẹ nise, ati lati gbe isin otitọ rẹ ati iwa rere leke. Baba mbẹ, fi ore-
ọfẹ fun gbogbo awọn Bisopu, ati Alagba, ki wọn ki o le ma fi iwa ati ẹkọ wọn gbe
ọrọ rẹ otitọ ti o ni iye kalẹ, ki wọn ki o si le ma se ise ipin-funni awọn
Sakramẹnti rẹ mimọ, bi o ti tọ ati bi o ti yẹ: Ki o si fi ore-ọfẹ rẹ mbẹ fun gbogbo
eniyan rẹ; ati pẹlupẹlu fun ọjọ yi ti o wa nihin nisinsin yii; pẹlu ọkan tutu ati
ọwọ ti o yẹ ki wọn ki o ma gbọ, ki wọn ki o si ma gba ọrọ mimọ rẹ; ki wọn ki o ma
sin o nitotọ ni mimọ iwa ati ni ododo ni ọjọ ayé wọn gbogbo. Awa si n fi iparamọ
bebe lodo rẹ ninu ore rẹ, Olúwa, lati rẹ on ati ran gbogbo wọn lowo ni ayé ti n
koja yi, awọn ẹni ti o wa ninu ise, ni ibinujẹ, ni aini, ninu aisan, tabi ninu
ipọnju miran. Awa si n fi ibukun fun Orukọ mimọ rẹ pẹlu, nitori gbogbo awọn
eniyan rẹ ti o ti fi ayé yi sile ni igbagbọ ati ni iberu rẹ; awa mbebe lodo rẹ, ki
iwọ ki o fi ore-ọfẹ fun wa bẹẹ, lati ma tọpa iwa rere wọn, ati pẹlu wọn ki awa ki o
le se alabapin ijọba ọrun rẹ: Baba, fi eyi funni, nitori Jesu Kristi Onilaja ati
Alagbawi wa nikansoso. Amin.
Bi oore anu tabi ẹbun ko ba si, a o fo ọrọ wọnyii, (gba ore anu ati ẹbun wa)
ni aika wọn.
ỌRỌ IYANJU
OLUFẸ ọwọn, ni ọjọ- oni, emi n gbero, nipa iranlọwọ Ọlọrun, lati se ipinfunni
Sakramenti Ara oun Ẹjẹ Kristi ti o ni itunu julọ, fun gbogbo awọn ẹni ti ọkan wọn
ba fa si i ni ifọkansin Ọlọrun; lati gba a ni iranti Agbelebu ati Iya-rẹ ti o toye;
nipa eyi kan naa ti awa n ri imukuro ẹsẹ wa gba, ti a si n mu wa di alabapin ijọba
mbẹ. Nje nitori naa ise wa ni lati fi iparamọ ati tọkantọkan dupẹ bi o ti to julọ
lọwọ Ọlọrun Olodumare Baba wa ti mbẹ ni ọrun, nitori ti o fi Jesu Kristi ọmọ rẹ
Olùgbàlà wa funni, ki ise kiki lati ku fun wa, sugbọn pẹlu lati ma se Ounjẹ ati
ohun ibo-ni ti emi ni Sakramenti mimọ naa. Bi o ti jẹ ohun mimọ ati ohun itunu fun
awọn ti o gba a bi o ti yẹ, ti o si se ohun ewu fun awọn ti o laya lati gba a layé;
ise mi ni lati gba yin niyanju niwoyi, lati ro bi ohun ijinle mimọ naa ti tobi to,
ati ewu nla ti aigba a bi o ti yẹ; bẹni ki eyi ni ki o si wa ọkan yin jalẹ koro,
(ki ima se ni awa afowota, bi awọn ẹlẹtan niwaju Ọlọrun; sugbọn be) ki ẹyin ki o le
wa ni mimọ ati ni aileri si iru Ase mbẹ yi, ninu asọ-iyawo ti Ọlọrun n fẹ ninu ọrọ
mimọ rẹ, ki a si le gba yin ni alabapin ti o yẹ ti Tabili mimọ naa.
Ọna ati ipa lati wa sibẹ niyi; Ikini, ki ẹyin ki o fi ilana ofin Ọlọrun wadi
iwa ati ise yin; ninu ohunkohun ti ẹyin ba si woye pe, ẹyin ti se, iba se ni ifẹ,
ni ọrọ ẹnu, tabi ni ise, ninu rẹ ni ki ẹyin ki o pohunrere ẹkun ẹsẹ yin, ki ẹyin ki
o si jẹwọ rẹ fun Ọlọrun Olodumare, ki ẹ si pinnu lati tun iwa yin se. Bi ẹyin ba
si woye pe ẹsẹ yin ki ise kiki si Ọlọrun nikan, sugbọn si ẹnikeji yin pẹlu; njẹ ki
ẹyin ki o ba wọn laja; ki ẹyin ki o si mura ati san ẹsan pada fun wọn, ati lati tu
wọn ninu gẹgẹ bi o ti wa ni ipa yin, nitori ibi, ati iwosi ti ẹ se wọn; ki ẹyin ki
o si ma mura bẹẹ gẹgẹ lati dariji awọn ẹlomi ti wọn si ti se yin, bi ẹyin ti n fẹ
idariji ẹsẹ yin lowo Ọlọrun: nitori bi e ko ba se be, gbigba Idapọ mimọ na yoo wulẹ
mu ẹbi yin di pupọ. Nitori naa bi enikan ninu yin ban se asọrọ-odi si Ọlọrun,
adena, tabi ase-bajẹ ọrọ rẹ, agbere, tabi alarankan, tabi onilara, tabi ẹni ti o wa
ninu ẹsẹ, buburu miran, e ronupiwada ẹsẹ yin, bikose be, mase wa si ibi Tabili mimọ
na; nitori lẹhin igba ti o ba ti gba Sakramẹnti mimọ naa tan, ki esu mase ma ba wo
inu rẹ, bi o ti wo inu Judasi, ki o si fi ẹsẹ gbogbo kun inu rẹ, ki o si mu ati ara
ati ọkan rẹ lo si inu iparun.
Ati nitori bi ko ti yẹ, ki ẹnikẹni ki o wa si Idapọ mimọ naa laigbẹkẹle anu
Ọlọrun patapata, ati laini ibajẹ ọkan: nitori naa bi ẹnikẹni ninu yin ko ba ni
ibalẹ ọkan lẹhin ọrọ wọnyii, sugbọn ti n fẹ itunu ati imọran si i, ki o to mi wa,
tabi ki o to Iransẹ Ọlọrun miran lo ti o moye ti o si gbọn, ki o le ri anfani
ifiji ẹsẹ, pẹlu imọran ati ẹkọ niti ohun ẹmi, lati mu ọkan rẹ balẹ, ati lati mu
gbogbo onnu ati iyemeji kuro.
ẸYIN ti o ronupiwada ẹsẹ yin nitotọ ati tọkantọkan, ti ẹyin si wa ninu ifẹ
ati ifẹni si ẹnikeji yin, ti ẹyin si n fẹ lati ma rin ni iwa titun, lati ma tọpa
ofin Ọlọrun, ati lati ma rin lati isinsin yii lọ ni ọna mimọ rẹ. Ẹ fi igbagbọ sunmọ
ihin, ki ẹ si gba Sakramẹnti mimọ yi fun itunu yin; ki ẹ si fi iparamose ijẹwọ fun
Ọlọrun Olodumare, ki ẹ si fi ọkan tutu kunlẹ ni ekun yin.
IJẸWỌ
ỌLỌRUN Olodumare, Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Ẹlẹda ohun gbogbo, Onidajọ
gbogbo eniyan; Awa jẹwọ, awa si n pohunrere ẹkun ọpọlọpọ ẹsẹ ti awa ti n da, ati
iwa buburu wa. Ti awa ti n hu nigbakugba, ni ero, ni ọrọ, ati ni iwa hihu, si
Ọlanla iwa mimọ rẹ. Awa n tọ ibinu ati irunu rẹ ti o to julọ si ara wa. Tọkantọkan
ni awa ronupiwada, Awa si n kaanu isise wa wọnyi lati inu wa; Ẹdun ni iranti wọn da
fun wa; Ẹru wọn ko se igbe. Saanu fun wa, Saanu fun wa Baba alanu julọ; nitori Jesu
Kristi Ọmọ rẹ Olúwa wa, Dariji gbogbo eyi ti o ti kọja ji wa; Ki iwọ ki o si
fifunni lai lẹhin eyiyi, ki awa ki o le maa sin, ki a le ma wu ọ. Ni ọtun iwa, Fun
ọla oun ogo Orukọ rẹ; Nitori Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
IFIJI
ỌLỌRUN Olodumare, Baba wa ti mbẹ ni ọrun, ẹni ti o ti inu anu rẹ nla se ileri
idariji ẹsẹ fun gbogbo awọn ti o tinu ronupiwada, ati ti wọn si fi igbagbọ otitọ
yipada si i: Ki o saanu fun yin: ki o dariji yin, ki o gba yin kuro ninu ẹsẹ yin
gbogbo; ki o mu ẹsẹ yin duro, ki o si mu yin ni ara le ninu ore gbogbo; ki o si mu
yin de inu iye ti ko nipẹkun; nitori Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
O YẸ jọjọ, o tọ, isẹ isin wa si ni, nigba gbogbo, ati nibi gbogbo, ki awa ki
o ma dupẹ lọwọ rẹ, Olúwa, *Baba Mimọ, Olodumare, ayérayé Ọlọrun.
*Ọrọ wọnyii, Baba Mimọ, ni ki a fo ni ọjọ Ọlọrun Mẹtalọkan.
Nihin yii ni ki Alagba ki o gba adura naa ti a yan silẹ fun ọjọ ọtọ, tabi eyi.
NITORI NAA pẹlu awọn Angẹli ati awọn Olori Angẹli, ati pẹlu gbogbo awọn egbe
ọrun, awa yin, awa si n gbe Orukọ rẹ ti o ni ogo ga; awa si yin Ọ titi lai pe,
Mimọ, mimọ, mimọ, Olúwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ọrun oun ayé kun fun ogo rẹ: Ogo ni
fun Ọ.
Ni Ọjọ-isinmi ti Mẹtalọkan.
ẸNI TI ise Ọlọrun kan, Olúwa kan; ki ise kiki Ẹnikansoso, sugbọn Ẹni-mẹta ni
Ohun iwa kan. Nitori eyi ti awa gbagbọ ni ti ogo Baba, oun naa ni awa gbagbọ ni ti
Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ pẹlu, laisi iyatọ tabi aidọgba. Nitori naa pẹlu awọn Angli,
&c.
Nigba naa ni Alagba yoo kunlẹ lẹba Tabili Olúwa, ni orukọ awọn ti yoo wa si Idapọ,
yoo si gba adura yii.
OLÚWA alaanu, awa ko dagba lati wa si Tabili rẹ yi, ni igbẹkẹle ododo ara
wa, bikose ni ọpọlọpọ anu rẹ nla. Awa ko yẹ to bẹẹ lati sa eerun akara labẹ Tabili
rẹ. Sugbọn iwọ ni Olúwa naa, iwa ẹni ti ise ati saanu nigbagbọ: Nitori naa, fifun
wa Olúwa olore-ọfẹ, lati jẹ ẹran-ara Jesu Kristi Ọmọ rẹ ọwọn, ati lati mu ẹjẹ rẹ
bẹẹ, ki ara rẹ ki o le sọ ara ẹsẹ wa di mimọ. Ati ki ẹjẹ rẹ iyebiye le wẹ ọkan wa
nu, ki awa ki o si le ma gbe inu rẹ titi lai, ki oun ki o si ma gbe inu wa. Amin.
Nigba ti Alagba ba duro niwaju Tabili, ti o si to Akara ati Waini lẹsẹẹsẹ tan, yoo
gba Adura Isọ-di-mimọ pe:
ỌLỌRUN Olodumare, Baba wa ti mbẹ ni ọrun, ẹni ti o ti inu iyọnu anu rẹ fi
Jesu Kristi ọmọ rẹ nikansoso funni lati jiya iku lori agbelebu fun idande wa; (nipa
ẹbọ kan ti o fi ara rẹ ru lẹkan soso) ẹni ti o ru ẹbọ itẹnilọrun, ẹbọ arukun, ati
aruda, ẹbọ ti o tọ, fun ẹsẹ gbogbo ayé; o si da a silẹ, ati ninu Ihin-rere rẹ mimọ,
o fi ohun silẹ fun wa lati ma se e titi, ni iranti iku rẹ iyebiye, titi yoo si fi
fun pada wa; Gbọ tiwa, Baba alanu julọ, gidigidi ni awa n fi irẹlẹ ohun bẹbẹ lọdọ
rẹ; ki o si fifunni, ki awa ti n gba akara ati waini ẹda rẹ wọnyii, gẹgẹ bi idasilẹ
mimọ Ọmọ rẹ Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ni iranti iku oun iya rẹ, ki a le se alabapin
Ara oun Ẹjẹ rẹ ti o ni ibukun julọ; ni oru ọjọ na ti a fi i han, ẹni ti o mu Akara;
nigba ti o si ti dupẹ, o bu u, o si fi fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi pé, Gba, jẹ, eyi
yi ni Ara mi ti a fifun yin: Ẹ maa se eyi ni iranti mi. Bẹ gẹgẹ lẹhin Ounjẹ o gba
Ago; nigba ti o si ti dupẹ, o fifun wọn, wi pé, Gbogbo yin ẹ mu ninu eyi; nitori
eyi ni Ẹjẹ mi ti Majẹmu Titun, ti a ta silẹ fun yin ati fun ẹni pupọ fun imukuro
ẹsẹ: Nigbakugba ti ẹyin ba n mu u, ẹ ma se eyi ni iranti mi. Amin.
Ipinfunni Akara
ARA Jesu Kristi Olúwa wa ti a fifun ọ, ki o pa ara ati ọkan rẹ mọ titi iye ti
ko nipẹkun. Gba eyi jẹ, ni iranti pe Kristi ku fun ọ, ki iwọ ki o si ma fi oun se
Ounjẹ je ni okan rẹ ni igbagbọ, pẹlu idupe.
Nigba naa ni Alagba yoo gba Adura Olúwa, awọn eniyan yoo wi tẹle e
BABA wa ti mbẹ ni mbẹ, ki a bọwọ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni
ki a se ni ayé, bi wọn ti n se ni ọrun. Fun wa ni Ounjẹ oojọ wa loni. Dari ẹsẹ wa
ji wa, Bi a ti n dari ẹsẹ ji awọn ti o sẹ wa. Ma fa wa sinu idẹwo; Sugbọn gba wa
lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, agbara ni tirẹ, lailai. Amin.
Tabi eyi,
OLODUMARE ati lai Ọlọrun alaye, tọkan tọkan ni awa fi n dupẹ lọwọ rẹ, nitori
iwọ fi Ounjẹ ẹmi ti ara ati ẹjẹ iyebiye Ọmọ rẹ Olùgbàlà Jesu Kristi bọ awa, ti o
gba ohun ijinlẹ mimọ wọnyii bi o ti yẹ; ti o si fi bẹẹ mu ki ojurere ati ore rẹ si
wa, ki o da wa loju; ati pe eya ara Ijinlẹ ọmọ rẹ papa ni awa ise, eyini ni egbe
gbogbo awọn onigbagbọ alabukun fun, ti wọn si ise ẹni ireti ijogun ijọba rẹ ti ko
nipẹkun, nipa itoye iku ati iya iyebiye ti ọmọ rẹ ọwọn. Gidigidi ni awa si n fi
irẹlẹ bẹbẹ lọdọ rẹ, Baba mbẹ, ki iwọ ki o fi ore-ọfẹ rẹ ran wa lọwọ bẹẹ, ki awa ki
o le duro titi ninu ẹgbẹ mimọ naa, ki awa ki o si ma se iru ise rere wọnni, ti iwọ
ti la silẹ fun wa, lati ma rin ninu wọn; nipasẹ Jesu Kristi Olúwa wa, pẹlu iwọ ati
Ẹmi Mimọ , ẹni ti gbogbo ọla oun ogo wa fun, ayé ainipẹkun. Amin.
OGO ni fun Ọlọrun ni oke mbẹ, ati ni ayé alafia, ifẹ inu rere si eniyan. Awa yin ọ,
awa n fi ibukun fun ọ, awa n fori balẹ fun ọ, awa yin o logo, awa n dupẹ lọwọ rẹ
nitori ogo rẹ nla, Ọlọrun Olúwa, Ọba ọrun, Ọlọrun Baba Olodumare.
Olúwa, ọmọ bibi nikansoso naa Jesu Kristi; Ọlọrun Olúwa, Ọda-aguntan Ọlọrun, Ọmọ
Baba, ẹni ti o ko ẹsẹ ayé lo, saanu fun wa. ẹni ti o ko ẹsẹ ayé lo, saanu fun wa.
Ẹni ti o ko ẹsẹ ayé lo, gba adura wa. Ẹni ti o joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba, saanu
fun wa.
Nitori iwọ nikan ni mimọ; iwọ nikan ni Olúwa; iwọ nikan, Kristi, pẹlu Ẹmi
Mimọ, ni o ga julọ ninu ogo Ọlọrun Baba. Amin.
Ibukun
ALAFIA Ọlọrun ti o ta gbogbo oye eniyan yọ, ki o pa yin ni aya oun ọkan mọ ni
Imọ oun ifẹ Ọlọrun, ati ti Jesu Kristi ọmọ rẹ Olúwa wa; ati ibukun Ọlọrun
Olodumare, ti Baba, ti Ọmọ, ati ti Ẹmi Mimọ , ki o wa ninu yin, ki o si ma ba yin
gbe nigba gbogbo. Amin.
Adura
OLÚWA, fi anu ran wa lọwọ, ninu ẹbẹ ati adura wa wọnyii, ki iwọ ki o si fa
ọkan awọn ọmọ-ọdọ rẹ si ati ni igbala ti ko nipẹkun; ninu ayida ati agbako ayé iku
yi, ki a le ma dabo bo wọn titi nipa iranlọwọ ore-ọfẹ rẹ; nipasẹ Jesu Krisiti Olúwa
wa. Amin.
OLÚWA Olodumare ati ayérayé Ọlọrun, fiye si ni, awa mbẹbẹ lọdọ rẹ, lati fi
ọna han wa, lati sọni di mimọ, ati lati se akoso ọkan ati ara wa, ni ọna ati ise
ofin rẹ; ati nipasẹ abo rẹ ti o lagbara julọ, nihin yii ati lai, ki a le ma pa wa
mọ ni ara ni ọkan; nipasẹ Jesu Kristi Olúwa ati Olùgbàlà wa. Amin.
ỌLỌRUN Olodumare, fifun wa awa mbẹbẹ lọdọ rẹ ki gbogbo ọrọ ti a fi ode eti wa
gbọ loni, nipa ore-ọfẹ rẹ, ki a gbin wọn si wa ni ọkan, ki wọn ki o le ma so eso
iwa rere ninu wa, fun ọla ati iyin Orukọ rẹ, nitori Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
OLÚWA, fi ore-ọfẹ rẹ julọ sanu wa ni gbogbo sisẹ wa, ki o si ma fi iranlọwọ
rẹ titi sun wa si iwaju; ni gbogbo ise wa ti a bẹrẹ si, ti a n se lọ, ti a si n se
pari lọdọ rẹ, ki awa ki o le ma yin Orukọ mimọ rẹ ni ogo, ati nikẹhin nipa anu rẹ,
ki a le ni iye ti ko nipẹkun; nipasẹ Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
ỌLỌRUN Olodumare, Olorisun ọgbọn gbogbo, iwọ ẹni ti o mọ aini wa ki a to
bere, ati aimọye wa ni ibere; Awa mbẹbẹ lọdọ rẹ, ki iwọ ki o saanu ailera wa; ati
ohun wọnni, nitori alayé wa ti awa ko gbọdọ tọrọ, ati nitori ifọju wa ti awa ko le
bere, fiyesi lati fifun wa, nitori ẹyẹ ọmọ rẹ Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
ỌLỌRUN Olodumare, iwọ ẹni ti o ti se ileri lati gbọ ẹbẹ awọn ti n tọrọ ni
Orukọ Ọmọ rẹ; Awa mbẹbẹ lọdọ rẹ, fi aanu de eti rẹ silẹ si awa ti n gbadura, ti a
si mbẹbẹ lọdọ rẹ nisinsin yii; ki o si fifunni, ki ohun wọnni, ti awa fi igbagbọ
bẹbẹ gẹgẹ bi ifẹ rẹ, ki a le ri wọn gba dajudaju, fun iranwọ aini wa, ati igbẹkẹle
ogo rẹ, nipasẹ Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.