Muestra Apola Odù Ese Ifá Nla, Templo Oyeku Fun

Descargar como pdf o txt
Descargar como pdf o txt
Está en la página 1de 17

LOS MEJIS |

1.0. EJI-OGBE.
Eji Ogbe 1

ẸSẸ –KINNI.

Ire (Bendicion)

Ifa nsọ feleyii wipe keleyii o rubọ nibẹ, koma ba sanwọ ire ti nwa. Eleyii nware. Ko kọkọ rubọ
nibẹ. Gbogbo ire ti nwa, Ifa lọwọ rẹ yoo to o, toba tile rubọ. Sugbọn tiko bati rubọ, kole rire yi o.
Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, koma ba sanwọ ire ti nwa loju Eji Ogbe. Nibi tifa naa gba tisọ bẹẹ ni
o. Ifa na sọ pe:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio para que no pieda la bendicion que esta
buscando. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio primero. Ifa dice que esta persona
conseguira todas las bendiciones que esta buscando si hace el sacrificio. Pero si esta persona no
hace el sacrificio, no conseguira esa bendicion. Ifa dice que debe hahcer el sacrificio para que no
pieda la bendicion que esta buscando en el signo de Eji-Ogbe. Ifa lo dice asi con este verso;
QUE:

Ọtọtọtọ, (Son separados)

Ọrọrọrọ, (Son separados)

Ọtọtọ laa jẹpa. (Separados se come el cacahuetes)

Ọtọtọ nla jẹ Imumu. (Separados se come el “Imumu”)


Ohun tori tori, (Lo que esta destinado para uno, es de uno)

Ohun tore tore (La bendicion de uno es de uno)

N laa fọba Makin nile Iranje (Es lo que se regala al Rey Makin en la casa de
Iranje)

Ko ba le fohun tori, tore, tani lọrẹ (Para que puede regular las bendiciones y lo
que estaba destinado para uno a uno)

A dia fun Ogo-tẹẹrẹ (Se adivino Ifa para Ogo-tẹẹrẹ)

Eyiti ngbogun lọ Ẹhinwọran. (El que iba de guierra a Ẹhinwọran)

Ogo-tẹẹrẹ lorukọ a npoko. (Ogo-tẹẹrẹ es el nombre que llamamos al pene)

Ẹhinwọran lorukọ a npobo. (Ẹhinwọran es el nombre que llamamos a la


vergina)

Eewọ oriṣa oko kii jagun ilobo ko sanwọ o. (Tabues de los Orisas, el pene no puede luchar
con al vergina y salir vacio)

ASẸ-IFA:- Ifa ni wipe keleyii o rubọ nibẹ. Ifa leleyii koni sanwọ ire ti nwa nibẹ. Gbogbo ohun
ti nwa yoo to lọwọ, toba ti rubọ nibẹ, toba ṣẹtutu fun AWỌN AIYE. Ifa ni pẹlu irọrun lọwọ rẹ
yoo fi tẹ nkan ti nwa loju Eji Ogbe.

ASẸ-IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que no sale con las manos
vacios en la bendicion que esta buscando. Ifa dice que esta persona conseguira con comodidad
todos lo que esta buscando si hace el sacrificio y ofrecimientos a los BRUJOS/AS en el signo de
Eji-Ogbe.

Eji Ogbe 2

ẸSẸ KEJI.

Ayẹwo iku ( Investigar la muerte)


Ifa ni wipe eleyii ni obìnrin pupa nile, o niyawo pupa nile, Ifa niki o rubọ nitori rẹ, kiku o ma
baa pobinrin yi meleyii lọwọ ni kiakia, kẹmi-rẹ o le ba gun. Ifa leleyii ni obinrin pupa nile, ko
rubọ nitori rẹ, kiku o ma paa mọ lọwọ. Nibi tifa naa tisọ bẹẹ re o, wipe obinrin pupa kan nu ninu
ile eleyii, ko rubọ nibẹ kiku o maa paa mọ lọwọ. Ifa naa sọ pe:

Si Ifa dice que NO en el signo de Eji-Ogbe. Ifa dice que esta persona tiene una mujer de color
clara en su casa. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio para esta mujer de color clara,
para que la muerte no mata a esta mujer rapidamente, para que ella puede tener larga vida. Ifa lo
dice asi con este verso, que esta persona tiene una mujer de color clara en su casa y que debe
hacer el sacrificio para esta mujer de color clara, para que la muerte no mata a esta mujer
rapidamente; QUE:

Sinimọ-Sinimọ, (Confunde uno con otro, confunde uno con otro)

A dia fun obinrin pupa rororo (Se adivino Ifa para una mujer clara y bonita)

Eyiti nṣeyawo Ọrunmila (Que era la esposa de Ọrunmila)

Nijọti nlọ re naya-iku lọja Ejigbomẹkun. (El dia que iba a pegar a la madre de la muerte en
el mercado de Ejigbomẹkun)

Sinimọ nlọ sọja Ejigbomẹkun. Nigba to dọja Ejigbomẹkun, o baya kan pade nibẹ. Sugbọn iya-
iku lẹni toba pade. Nigba tija de sarin wọn, loba naya yi gidi. Awọn eniyan ba nwipe: !ah iya-iku
lo na!. Heh?! Iru iya wo ni! Kínni njẹ iya-iku, komọ itumọ iku. O na iya yi debi wipe, ẹmi rẹ si fẹ
bọ. Nigba tiyawo Ọrunmila wa dele, loba sọ fun ọkọ-rẹ. O ni: !Ah Baba! O loun baya kan pade
lọja Ejigbomẹkun loni. O ni, loba fẹ roun fin, loun ba naya yi. Ọrunmila níru iya wo lowa na? O
ni, iya-iku niwon npe e. !Ah! Ọrunmila ni, gbaga. Iya-iku lona. !Ah! Iru kinni iwọ obinrin yii wa
ṣe yi o. Tabi o mọ ohun ti o nwi ni? Ah, o loun na pupọ ni ṣẹ. O loun mohun toun nwi. Iya-iku
ni, o ni iya-iku ni.
Ọrunmila ba sare gbefa kalẹ, lo dafa. Ifa basọ fun Ọrunmila pe, ko TETE rubọ o, kiku ma
pobinrin yii mọ lọwọ o. Kosi tete fun gbogbo awọn obinrin to pupa nile rẹ, ko kunwọn ni buje, ki
gbogbo wọn o dudu o. Tori tiku ba robinrin pupa nile rẹ, iku yoo mu gbogbo won lọ o. Loju ẹsẹ,
Ọrunmila tiwa gbogbo ohun tiwọn ni kọrunmila ru lẹbo, o ti ru u. O gbọ riru, o ru. O gbọ titu, o
tu. O gbọ ọharahara ẹbọ loju ọpọn, o ha. Gbogbo ohun tiwon ni koṣe , o tiṣe e. O ti yẹ o. O ti
bawon jewe Ifa. O tiwa buje lọ, a npe kinnikan ni buje. Ta bati fi kun eniyan bayii, eniyan pupa
yoo dudu ni kiakia ni. Ọrunmila tiwa buje lọ. Wọn ti ṣetutu, wọn ti kun gbogbo obinrin to pupa
nile Ọrunmila nibuje.

Sinimọ fue al mercado de Ejigbomẹkun. Cuando ella llego al mercado de Ejigbomẹkun, se


encontro con una vieja que era la madre de la muerte. Pero Sinimọ no sabia quien era la vieja.
Ocurrio discurciones entre la vieja y Sinimọ. Sinimọ pego a la vieja, la madre de la muerte. Las
gentes en el mercado decian que: !Ah, estas pegando a la madre de la muerte!. Sinimọ dijo: !que
significa la madre de la muerte! Sinimọ pego a la madre de la muerte hasta el punto que le
faltaba poco para matarla. Cuando Sinimọ llego a casa, se lo conto a su marido Ọrunmila, dijo
que ella encontro con una vieja en el mercado de Ejigbomẹkun hoy, dijo que la vieja la falto
respeto y que ella pego a la vieja bastante. Ọrunmila pregunto a Sinimọ que: ?Como se llama la
mujer vieja?. Sinimọ dijo que las gentes del mercado la llaman “la madre de la muerte”.
!Ọrunmila grito que ella ha pegado a la madre de la muerte. Ọrunmila pregunto a Sinimọ que si
ella estaba segura de lo que estaba hablando!. Sinimọ contesto a Ọrunmila que ella estaba segura
que era la madre de la muerte.

Enseguida Ọrunmila consulto a Ifa. Ifa le dijo que debe hacer el sacrificio URGENTEMENTE,
para que la muerte no mata a su esposa Sinimọ. Ifa dijo que Ọrunmila debe pintar a todas sus
esposas de colores claras con “buje” URGENTEMENTE. Si la muerte llega a la casa de
Ọrunmila, matara a todas las esposas de Ọrunmila de colores claras. Enseguida Ọrunmila busco
todas las cosas necesarios para el sacrificio y hizo el sacrificio. Ọrunmila oio el sacrificio y
sacrifico. Oio el ofrecimiento y ofrecio. Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion
de Ifa. Ọrunmila hizo todos lo que le mandaron a hacer. Preparo las hierbas de Ifa. Ọrunmila
busco “buje” y pinto a todas sus esposas con colores claras en su casa con “buje”. Si se pinta a
una persona de color clara con “buje” su color se cambia al color negro enseguida.

Nigba to dọjọ keji, bayi niku se dele Ọrunmila. Iku sini kondo kan, kondo yi ko gun ju bayi lọ.
Nigba tiku dewaju ita Ọrunmila bayi. Iku kan ju kondo soke bayi, loba joko lee. O ni: Iwọ
Ọrunmila! Ọrunmila loun njẹ. O niyawo rẹ naya oun lọja Ejigbomẹkun lana. Ọrunmila ni kii
ṣeyawo oun! Ah! O ni, kii ṣeyawo rẹ bawo. Ọrunmila ni, kii ṣeyawo oun. Kii ṣeyawo rẹ.
Ọrunmila ni, kii ṣeyawo oun. Kii ṣewọ lo lobinrin to pupa roro kan bayii. Ọrunmila loun ko
lobinrin pupa nile. Iku ni o lobinrin pupa nile. O ni: bẹẹ ni. Iku lo dara, ko ko gbogbo awọn
obinrin inu ile rẹ jade nigba naa, koun yẹwọn wo.

Bi Ọrunmila ti ko gbogbo awọn obinrin towa ninu ile jade niyi patapata. Ọrunmila si niyawo
pupọ. Niku wa laarin wọn lo garara. Niku wa nwobinrin pupa nibẹ. Iku ko robinrin pupa nibẹ. O
lawọn lọ, o lawọn bọ, ọ rin lọ, o rin bọ, ko robinrin pupa. !Gbaga! Niku bu sẹkun, o niya lo jẹun
toto bayii. Ṣe kii ṣeyawo rẹ ni. Ọrunmila ni kii ṣeyawo oun, o loun ko lobinrin pupa nile. Nigba
tiko robinrin pupa nibẹ, biku ṣe sunkun lọ niyi. Ni Ọrunmila ba nyin awọn awo rẹ, lawọn awo rẹ
ba nyin Ifa. Ọrunmila ni bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun wi o, bẹẹ gẹgẹ lawọn awo toun sọ. O ni:

El dia siguiente, la muerte llego a la casa de Ọrunmila. La muerte tenia un baston chiquitito.
Cuando la muerte llego al frente de la casa de Ọrunmila, saco su baston, tiro el baston arriba y la
muerte se sento encima del baston. La muerte dijo que: Tu Ọrunmila. Ọrunmila contesto a la
muerte que si. La muerte dijo que: tu esposa pego a me madre ayer en el mercado de
Ejigbomẹkun. Ọrunmila dijo que: no fue me mujer que pego a tu madre. La muerte pregunto que
no fue la mujer de Ọrunmila. Ọrunmila contesto que no fue su mujer. La muerte pregunto a
Ọrunmila que la mujer de color clara y bonita no era la esposa de Ọrunmila. Ọrunmila contesto
que no tenia ninguna mujer de color clara en su casa. La muerte dijo que Ọrunmila tenia que
sacar todas sus esposas para verlas.

Ọrunmila saco a todas sus esposas. Ọrunmila tenia muchas esposas y esposas de colores claras.
Ọrunmila y habia pintados todas sus mujeres de colores claras con “buje”. La muerte cruzo entre
todas ellas. La muerte ando para alla y para aca entre ellas y no vio a ninguna de ellas con color
clara. La muerte volvio a preguntar a Ọrunmila que no fue su mujer que pego a su madre.
Ọrunmila dijo que no y que el no tenia ninguna mujer de color clara en su casa. Cuando la
muerte no vio a ninguna mujer de color clara entre las esposas de Ọrunmila. La muerte se puso a
llorar y se fue. Ọrunmila empezo a alabar a sus awos y sus awos alabando a Ifa. Ọrunmila dijo
que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Sinimọ-Sinimọ, (Confunde uno con otro, confunde uno con otro)

A dia fun obinrin pupa rororo (Se adivino Ifa para una mujer clara y bonita)

Eyi ti ṣeyawo Ọrunmila (Que era la esposa de Ọrunmila)

Nijọti nlọ re naya-iku lọja Ejigbomẹkun. (El dia que iba a pegar a la madre de la muerte en
el mercado de Ejigbomẹkun)

Ẹbọ niwọn ni o ṣe (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

O si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Lo hizo)

Ko pẹ, ko jinna, (Pronto y no tan lejano)

Ifa wa bani laarin ṣegun. (Ifa ven a encontranos en el medio de


vencimiento)
Aarin ṣẹgun, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio de vencimiento se encuentra uno a
los pies del Rey de los Orisas)

O nṣe: (CANCION)

Iku sonibuje mọ, Sinimọ, Sinimọ (La muerte no reconocio a la persona que estaba
pintado con“buje”, confunde uno con otro, confunde uno con otro)

Aarun sonibuje mọ, Sinimọ, Sinimọ (La enfermedad no reconocio a la persona que esta
pintado con“buje”, confunde uno con otro, confunde uno con otro)

Ofo sonibuje mọ, Sinimọ, Sinimọ (La pedida no reconocio a la persona que estaba pintado
con“buje”, confunde uno con otro, confunde uno con otro)

Aseiri sonibuje mọ, Sinimọ, Sinimọ (Trabajando sin fruto no reconocio a la persona que
estaba pintado con“buje”, confunde uno con otro, confunde uno con otro)

Afaato sonibuje mọ, Sinimọ, Sinimọ (Haciendo esfuerzos para nada no reconocio a la persona
que esta pintado con“buje”, confunde uno con otro, confunde uno con otro)

Idamu sonibuje mọ, Sinimọ, Sinimọ (Problemas no reconocio a la persona que esta pintado
con“buje”, confunde uno con otro, confunde uno con otro)

ASẸ-IFA:- Ọrunmila bẹrẹ sini nyin Ifa niyi, tifa nyin Eledumare ree. Ifa leleyii niyawo pupa
nile. Ifa ni keleyii o TETE rubọ fun-un, ko TETE kun obinrin yi ni buje, kiku o ma baa pobinrin
yi meleyii lọwọ lọdun ni loju Eji Ogbe. Ifa lawọn iyawo ile eleyii ko gbọdọ ba ẹnikankakan ja
rara.

ASẸ-IFA:- Ọrunmila empezo a alabar a Ifa. Al mismo tiempo, Ifa alabando a Olodumare. Ifa
dice que esta persona tiene una mujer de color clara en su casa. Ifa dice que esta persona debe
hacer el sacrificio para ella URGENTEMENTE, pintarla con “buje”, para que la muerte no mata
a ella este ano en el signo de Eji-Ogbe. Ifa dice que las mujeres de la casa de esta persona no
debe peliarse con nadie.
2.0. OYEKU MEJI

ẸSẸ –KINNI.

Ayẹwo iku (Investigar la muerte)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, koma ba bawọn kuku ajọku loju Ọyeku-Meji. Ifa sini keleyii o sọra fun
nkan pupa lati maa lo. Koma wọṣọ pupa, toripe aṣọ pupa naa ni yoo gbẹmi rẹ la nigba tiku bade.
Tiku fẹ peleyii. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ nitori iku o. Ifa leleyii koni bawọn kuku ajọku loju
Ọyẹku-Meji o. Nibi tifa gba, to fisọ bẹẹ niyi o. Ifa ni:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que no muere entre multitudes de gentes
en el signo de Ọyeku-Meji. Ifa dice que esta persona debe tener cuidado en usar cosas rojas. Que
no debe usar la ropa roja, porque la ropa roja le salvara su vida cuando llega la muerte para
matarle. Ifa dice que debe hacer el sacrificio por la muerte. Ifa pide que esta persona no murira
entre multitudes de gentes en el signo de Ọyẹku-Meji. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Kijipa abita hanna-hanna (Kijipa abita hanna-hanna)

A difa fun Enlọjọ Aṣọ, (Se adivino Ifa para todas las ropas)

A bu fun Kẹlẹ. (Tambien se adivino Ifa para “Kẹlẹ”)

Kẹlẹ ru o, Kẹlẹ tu. (“Kẹlẹ” hizo el sacrificio, “Kẹlẹ” hizo el ofrecimiento)

Aṣọ toba ṣẹbọ kii rọrun. (La ropa que hizo el sacrificio no puede irse al
cielo/murirse)
Nigba igbawasẹ, wọn niki gbogbo awọn aṣọ patapata, kiwọn o rubọ . Kiwọn o ma ba bawọn
kuku ajọku o. Wọn kọ, wọn ko rubọ. Aṣọ pupa nikan lo rubọ. Ẹbọ rẹ si fin, ẹbọ rẹ da. Nigba
toya, akọsilẹ de, tiwon sọ fun wọn pe o nbọ. Niku ba bẹẹrẹ si pa gbogbo awọn aṣọ iyoku
patapata, nitoripe wọn ko rubọ, wọn ko ṣetutu. Aṣọ pupa to rubọ nijọ ọjọ naa, iku ba daa si, kọ pa
a.

Idi rẹ niyi, toku baku loni, wọn kii faṣọ pupa sinku. Ta bafẹ sinku, wọn a ni aṣọ eleyii pupa, ẹ
mafi sin o. Aṣọ eleyii pupa, ẹ mafi sin o. Bẹẹ ni, idi niyi tiwọn kii fi faṣọ pupa sinku. Nigba tiku
de, tiku nko gbogbo awọn aṣọ lọ, to daṣọ pupa si. Laṣọ pupa ba nyin awọn awo rẹ, lawọn awo rẹ
na wa nyin Ifa. O ni bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun sọ:

Al principio del mundo, dijieron a todas las ropas que deben hacer el sacrificio para que no
mueren entre multitudes. No hicieron el sacrificio. Solamente la ropa roja hizo el sacrificio. El
sacrificio de la ropa roja se levanto y se acepto. Llego el destino final de ellos y se lo habian
dichos a todos ellos. La muerte empezo a matar a todas las ropas, porque no hicieron el sacrifcios
y los ofrecimientos. La ropa roja que hizo el sacrificio en su dia, se salvo de la muerte, la muerte
no la mato.

Por esta razon, no se entierran los muertos con las ropas rojas hasta la fecha de hoy. Si quieremos
enterrar un muerto, las gentes decian que con ropas/telas rojas, no se puede enterrar los muertos.
Cuando llego la muerte, mato a todas las ropas, la muerte salvo a la ropa roja. La ropa roja
empezo a alabar a sus awos y sus awos alabando a Ifa, que asi mismo lo han adivinados y
cantados sus awos; QUE:

Kijipa abita hanna-hanna (Kijipa abi ita hanna-hanna)

A difa fun Enlọjọ Aṣọ, (Se adivino Ifa para todas las ropas)

A bu fun Kẹlẹ. (Tambien se adivino Ifa para “Kẹlẹ”)

Kẹlẹ ru o, Kẹlẹ tu. (“Kẹlẹ” hizo el sacrificio, “Kẹlẹ” hizo el ofrecimiento)

Aṣọ toba ṣẹbọ kii rọrun. (La ropa que hizo el sacrificio no puede irse al
cielo/murirse)

Ko pẹ o, ko jinna, (Pronto y no tan lejano)

Ifa wa bani laarin ṣegun. (Ifa ven a encontranos en el medio de vencimiento)


Aarin ṣẹgun, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio de vencimiento se encuentra uno a los
pies del Rey de los Orisas)

O nse: (CANCION)

Aṣọ toba ṣẹbọ kii rọrun. (La ropa que hizo el sacrificio no puede irse al
cielo/murirse)

Aṣọ toba ṣẹbọ kii rọrun. (La ropa que hizo el sacrificio no puede irse al
cielo/murirse)

Kẹlẹ ru (“Kẹlẹ” hizo el sacrificio)

Kẹlẹ tu (“Kẹlẹ” hizo el ofrecimientoo)

Aṣọ toba ṣẹbọ kii rọrun. (La ropa que hizo el sacrificio no puede irse al
cielo/murirse)

Aṣọ toba ṣẹbọ kii rọrun. (La ropa que hizo el sacrificio no puede irse al
cielo/murirse)

Kẹlẹ ru (“Kẹlẹ” hizo el sacrificio)

Kẹlẹ tu (“Kẹlẹ” hizo el ofrecimiento)

Aṣọ toba ṣẹbọ kii rọrun. (La ropa que hizo el sacrificio no puede irse al
cielo/murirse)

ASẸ-IFA:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, koma ba bawọn kuku ajọku, keleyii o masi lo nkan pupa.
Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, koma ba bawọn kuku ajọku loju Ọyẹku Meji.

ASẸ-IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que no muere entre multitudes
de gentes. Ifa dice que esta persona no debe usar las cosas rojas. Ifa dice que esta persona no
debe usar ropas rojas. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, para que no muere entre
multitudes de gentes en el signo de Ọyẹku Meji.
ẸSẸ KEJI.

Ire-Ọmọ (Bendicion hijo)

Ifa leleyii nmẹnuju ṣe irahun ọmọ. O si njẹ ibanujẹ fun-un wipe oun ko rọmọbi. Ifa ni keleyii o
rubọ nibẹ. Ifa leleyii yoo bimọ. Ti gbogbo iya ti njẹ lori ọmọ yoo si digbagbe. Ifa ni keleyii o ni
“ATIO” lẹbọ nibẹ ati OKETE tiwọn ko sun nina, tirun siwa lara rẹ lẹbọ nibẹ. Atio ni kinni ti a
ma fimọ-ọpẹ ṣe. Inu atio na la o kẹbọ rẹ si, nigba taba rubọ yi tan. Ifa leleyii yoo sabiamọ.Ibi tifa
gba tifa fisọ bẹẹ niyi.O ni:

Ifa dice que esta persona esta llorando por no tener hijo. Ifa dice que esta persona esta infeliz por
no tener hijo. Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio y tendra hijo. Ifa dice que todos lo
que esta sufriendo esta perona por no tener hijo que quedaran olividados. Ifa dice que debe tener
ATIO en su sacrificio, debe tener RATA GRANDE ( seco y que no esta hecho a la lena y con
pelos en su cuerpo) en su sacrificio. Atio se hace con las hojas de la palmera. Duespues de hacer
el sacrificio, el sacrificio se mete dentro de Atio para llevarlo a donde Ifa indica. Ifa dice que esta
persona tendra hijo. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ọyẹyẹ ṣẹ nla bọ loke. (Ọyẹyẹ esta amaneciendo desde arriba en el cielo)

Wọn ṣe bojumọ lo mọ (Pensaban que ya se ha amanecido el dia)

A difa fẹja (Se adivino Ifa para el pescado)

Eyiti nṣọmọ Onibu. (Que era el hijo del “Onibu”)

Wọn niki ẹja o rubọ nibẹ. Wọn ni toba ti rubọ o, ko sini OKETE pẹlu ATIO lẹbọ nibẹ. Wọn ni
yoo bimọ. Wọn ni yoo wa bimọ pupọ debi wipe, !ah! Wọn koni le mọye ọmọ rẹ. O si gbọ riru
ẹbọ, o ru. O gbọ titu, o tu. O gbọ ọharahara ẹbọ loju ọpọn, o ha. Ko pẹ o, ko jinna. Loba loyun, lo
ba bimọ. !Ah! Ni ẹja ba njo, loba nyọ. Ni ẹja ba nbimọ saa. Ni ẹja ba njo, ni ba nyọ, ni nyin
awọn awo, ni awọn awo rẹ wa nyin Ifa. O ni bẹẹ gẹgẹ ni babalawo toun wi, bẹẹ gẹgẹ ni
babalawo toun sọ:
Dijieron al pescado que debe hacer el sacrificio. Dijieron que si hace el sacrificio con la RATA
GRANDE y ATIO, tenra hijos. Dijieron que el pescado tendra muchos hijos hasta el punto que
nadie sabra las cantidades de hijos que tendra el pescado. El pescado oio el sacrificio y sacrifico.
Oio el ofrecimiento y ofrecio. Hizo caso a lo que salio en el tablero de la adivinacion. Pronto y
no tan lejano. El pescado se quedo embarazada y tuvo hijos. El pescado estaba feliz, empezo a
bailar y cantar, que asi mismo lo han adivinados y cantados sus awos; QUE:

Ọyẹyẹ ṣẹ nla bọ loke. (Ọyẹyẹ esta amaneciendo desde arriba en el cielo)

Wọn ṣe bojumọ lo mọ (Pensaban que ya se ha amanecido el dia)

A difa fẹja (Se adivino Ifa para el pescado)

Eyiti nṣọmọ Onibu. (Que era el hijo del “Onibu”)

Ẹbọ niwọn ni o ṣe, (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

O si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Lo hizo)

Riru ẹbọ ni fin tifi ngbeni. (Haciendo el sacrificio es lo que ayuda a uno)

Aitete ru teṣu ni da ladanu. (Apasiguando a Esu pronto desvia la mala suerte)

Ko pẹ o, ko jinna, (Pronto y no tan lejano)

Ifa wa bani ijẹbutu ọmọ. (Ifa ven a encontranos en la celebracion de bendicion


de hijo)

Ijẹbutu ọmọ, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de bendicion de hijo se encuentra
uno a los pies del Rey de los Orisas)

O nṣe (CANCION)

Sakun winni. (Sakun winni)

Sakun winni. (Sakun winni)

Ko sibi ta ti kan odo. (No hay sitio donde puedemos encontrar el rio)

Ta o ni kan ọmọ ẹja. (Y que no encontramos a los hijos del pescado)

Sakun winni. (Sakun winni)


Ọmọ ẹja ma tiẹ ti papọju. (Los hijos del pescado son demaciados)

ASẸ-IFA:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa leleyi yoo bimọ pupọ. Ifa losọ bẹẹ. Ifa ni keleyii o lọ
fọkanbale. Ifa tun mẹnu ba lori ọrọ ọlọmọ deyi naa ni. Ifa niya ọmọ ti njeleyii yoo si dohun
igbagbe.

ASẸ-IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona tendra
muchos hijos. Ifa dice que esta persona debe estar tranquila. Ifa volvio a institir que esta persona
esta sufriendo mucho por no tener hijo. Ifa dice que sus sufrimientos por no tener hijos se
quedaran olividados.

ẸSẸ KẸTA.

Ire Ọmọ (Bendicion de hijo)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni yoo gbagbe gbogbo ohun toju rẹ nri lori ọmọ yoo dohun igbagbe
patapata.Ibi tifa gba tifa fisọ bẹẹ nii. O ni:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que todos lo esta persona esta
sufriendo por no tener hijo se quedaran olividados. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Ọgan lo danu, o rọmi sinu. (Ọgan hizo su estomago y con agua dentro)

Ọlọrọ ni rọmi ọrọ sikun (La persona que esta pensando lo lleva en su estomago)

A dia fun Alapa N yawe, (Se adivino Ifa para Alapa N yawe)
Ọmọ a mu EEGUN ẸJA rubọ nitori ọmọ (Hijo del que usa HUESO DE PESCADO para hacer
el sacrificio para tener hijo)

Maja maja la kalapa. (“Maja maja” es como saludamos a Alapa)

Alapa o ku ewu. (“Alapa” en hora buena)

Alapa o ku ewu ọmọ ẹja, (“Alapa” en hora buena del hijo de pescado)

Ero Opo, ero Ọffa (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)

Ẹ wa bani nijẹbutu ọmọ. (Ustedes ven a encontranos en la celebracion de


bendicion de hijo)

Ijẹbutu ọmọ, nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de bendicion de hijo se encuentra
uno a los pies del Rey de los Orisas)

ASẸ-IFA:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa lọmọ sun bọrọ, ti gbogbo iya ti njẹ lori ọrọ ọmọ yoo si
dohun igbagbe.

ASẸ-IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio, Ifa dice que tendra hijo pronto. Ifa
dice que todos lo esta persona esta sufriendo para no tener hijo se quedaran olividados.

ẸSẸ KẸRIN.

Isegun Ọta lori Ọmọ (Investigar el vencimiento de enimigo sobre hijo)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa niki o lọ BỌ ṢANGO nibẹ. Ifa niṣẹgun yoo de feleyii. Gbogbo
awọn tiwọn beleyii ṣọta, tiwon ngbogun tii, tiwon kofẹ jẹki o ni laari laiye, tiwon kofẹ jẹki oun
na dọlọmọ laiye. Ifa niki o lọ BỌ ṢANGO. Ifa ni Ṣango ni yoo beleyii ṣẹgun nibẹ. Arabanbi ọmọ
ari igba ọta ṣẹgun. Ibi tifa gba tofi sọ bẹẹ niyi. O ni:
Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona debe DAR DE
COMER A SANGO. Ifa dice que hay vencimiento para esta persona. Ifa dice que todos los que
estan haciendos enimigos contra esta persona, los que estan batallandos y levantandos guierra
contra esta persona, los que no quieren verle prosperar, los que no quieren que esta persona sea
padre de hijo en la vida, Ifa dice que esta persona debe DAR DE COMER A SANGO. Ifa dice
que Sango le ayudara a vencer a sus enimigos. Arabanbi, el hijo del que encuentra dos cientas
piedras de rayos para vencer. Ifa lo dice asi con este verso; QUE:

Omi-igbo ni foju jaro. (El agua del bosque tiene cara como azul)

Omi-ọdan ni foju jaro ngbẹtẹ (El agua de la sabana tiene cara como azul “ngbẹtẹ”)

A dia fun Legbedi (Se adivino Ifa para Legbedi)

A bu fun ọbọ. (Tambien se adivino Ifa para el mono “ọbọ”)

Ẹbọ niwọn ni won o ṣe, (Les dijieron que deben hacer el sacrificio)

Wọn si gbẹbọ nibẹ, wọn rubọ. (Lo hicieron)

Ko pẹ o, ko jinna, (Pronto y no tan lejano)

Ifa wa bani laarin ṣegun. (Ifa ven a encontranos en el medio del vencimiento)

Aarin ṣegun nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En el medio de vencimiento se encuentra uno a los pies
del Rey de los Orisas)

ASẸ-IFA:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni keleyii o lọbọ ṢANGO nibẹ. Ifa lọna rẹ yoo la, yoo
si ṣegun. Ifa lọwọ rẹ yoo to gbogbo ohun ti nwa.

ASẸ-IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona debe DAR
DE COMER A SANGO. Ifa dice que sango le ayudara a vencer a sus enimigos.Ifa dice que su
camino abrira y vencera. Ifa dice que esta persona conseguira todos lo que esta intentando
conseguir

.
ẸSẸ KARUN.

Ire Ilọsiwaju. (Bendicion de prosperidad)

Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa ni keleyii o lọ BỌFA. Ifa lọrọ rẹ yoo loju nkan rere. Ifa nire yoo
teleyii lọwọ. Gbogbo ohun tosi deleyii laamu yoo rokun igbagbe patapata. Ifa niwọn yoo si fiṣe
olori ipo kan. Ifa ni pe wọn fẹ feleyii ṣolori, wọn yoo fiṣe olori ibikan. Tọrọ rẹ yoo dijo, ti yoo
dayọ. Nibi tifa gba tisọ bẹẹ tofi nire yoo teleyii lọwọ niyi. O ni:

Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona debe DAR DE
COMER A IFA, Ifa dice que sus cosas le saldran bien. Ifa dice que llegaran las bendiciones a
esta persona. Todos lo que estan molestandole, estorbandole y causandole problemas a esta
persona se quedaran olividados. Ifa dice que le van a hacer jefe de un cargo/puesto, que le van a
hacer el jefe en un sitio. Hiiin. Sus asuntos se convertiran en bailes y felicidades. Ifa lo dice asi
con este verso que le llegaran las bendiciones a esta persona; QUE:

Oguuluntu (Oguuluntu “Piedra redonda y rebostosa”)

Ọrọ bale dun giyan-giyan, (Palabra toco al suelo y sono rotundamente “giyan-
giyan”)

A dia fun Mọja, (Se adivino Ifa para Mọja)

Eyiti nṣawo rele Alapa. (El que iba a predicar a Ifa en la casa de Alapa)

Ẹni Mọja, a sai dalapa (Gentes de Mọja, se convertira en Alapa)

Ẹbọ niwọn ni o ṣe, (Dijieron que debe hacer el sacrificio)

O si gbẹbọ nibẹ, o rubọ. (Lo hizo)

Ero Opo, ero Ọffa (Pelegrino de Opo, pelegrino de Ọffa)

Ẹ wa bani nijẹbutu ire. (Ustedes ven a encontranos en la celebracion de


bendicion)
Ijẹbutu ire nlaa bani lẹsẹ ọbariṣa. (En la celebracion de bendicion se encuentra uno a
los pies del Rey de los Orisas)

ASẸ-IFA:- Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ. Ifa leleyii yoo jolori. Ifa lọrọ rẹ yoo dijo, ti yoo dayọ. Wọn
yoo si fiṣe olori nibikan loju Ọyẹku-Meji.

ASẸ-IFA:- Ifa dice que esta persona debe hacer el sacrificio. Ifa dice que esta persona sera
elegido el jefe en un sitio. Ifa dice que los asuntos de esta persona se convertiran en bailes y
felicidades. Ifa dice que esta persona sera elegido el jefe en un sitio en el signo de Ọyẹku-Meji.

3.0. IWORI MEJI


ẸSẸ –KINNI.

Ire Gbogbo. (Todas las bendiciones)

Ifa nitori nkankan leleyii ṣe dafa. Ifa leleyii ngbiyanju lati depo kan tabi kofẹ lọ sibikan fun ọrọ
aje. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ, kosi BỌ ẸLẸDA RẸ. Ko BỌRI RẸ. Ifa ni wipe ẹlẹda rẹ ni yoo tọọ
sọna nibẹ, ti yoo beleyii ṣẹgun nigba toba debi nkan na tan. Ifa pẹlẹda rẹ yoo ba ṣẹgun, tọwọ rẹ
yoo fi to nkan na. Ifa ni keleyii o rubọ nibẹ loju Iwori-Meji. Nibi tifa na gba tifa fisọ bẹẹ ni. O ni:

También podría gustarte