Jump to content

Teresa Wright

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Teresa Wright
Wright in 1953
Ọjọ́ìbíMuriel Teresa Wright
(1918-10-27)Oṣù Kẹ̀wá 27, 1918
Harlem, New York, U.S.
AláìsíMarch 6, 2005(2005-03-06) (ọmọ ọdún 86)
New Haven, Connecticut, U.S.
Resting placeEvergreen Cemetery
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1941–1997
Olólùfẹ́
Niven Busch
(m. 1942; div. 1952)

Robert Anderson
(m. 1959; div. 1978)
Àwọn ọmọ2

Muriel Teresa Wright (Oṣù kẹwàá ọjọ́ kẹta-dín-lọ́gbọ̀n, ọdún 1918 sí Oṣù kẹta ọjọ́ kẹfà, ọdún 2005) jẹ́ òṣèré Amẹ́ríkà kan. Wọ́n yàn-án lẹ́ẹ̀mẹ́jì fún Àmì-ẹ̀yẹ Akádẹ́mì fún Òṣèré Àtìlẹ́yìn obìnrin tó dára jùlọ: ní ọdún 1914 fún iṣẹ́ rẹ̀ tó gbé e jáde ní "The Little Foxes", àti ní ọdún 1941 fún Mrs. Miniver. Ní ọdún kan náà, wọ́n tún yàn-án fún Àmì-ẹ̀yẹ Akádẹ́mì fún òṣèré obìnrin tó dára jù lọ fún iṣẹ́ rẹ̀ nínú "The Pride of the Yankees, ní bi tó kọjú Gary Cooper. Wọ́n mọ̀ọ́ fún iṣẹ́ ṣíṣe rẹ̀ nínú Shadow of a Doubt ti Alfred Hitchcock (ní ọdún 1943) àti The Best Years of Our Lives (ọdún 1946) ti William Wyler.

Wright gba yíyán Àmì-ẹ̀yẹ Emmy mẹ́ta fún iṣẹ́ rẹ̀ ní Playhouse 90 apá tẹlifísàn gangan ti "The Miracle Worker" (ọdún 1957), ní ẹ̀yà Breck Sunday Showcase ìtàn "The Margaret Bourke-White", àti nínú àwọn eré jara CBS "Dolphin Cove" (ọdún 1989). Ó gba ìyìn ti àwọn Olùdarí fíìmù tí ó ga jùlọ, pẹ̀lú William Wyler, ẹni tí ó pè é ní òṣèré tí ó ní ìlérí jùlọ tí ó ti ṣe ìtọ́sọ́nà, àti Alfred Hitchcock, ẹni tí ó n'ífẹ sí ìgbaradì rẹ̀ ní kíkún àti alámọ̀dájú idákẹ́jẹ́.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Muriel Teresa Wright ní oṣù kẹwàá ọjọ́ kẹta-dín-lọ́gbọ̀n, ọdún 1918, ní Harlem, New York City, ọmọ obìnrin ti Martha Espy àti Arthur Hendricksen Wright, alákoso ìní ènìyàn.[2] Àwọn òbí rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀ nígbà tí ó sì wà ní kékeré. Ó dàgbà ní Maplewood, ní ilẹ̀ New Jersey, níbití ó ti lọ sí ilé-ìwé gíga, Columbia High School. Lẹ́hìn tí ó rí Helen Hayes nínú eré Victoria Regina ní kara Broadhurst ní New York City ní ọdún 1936.[3]

Àwọn itọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Teresa Wright". The Movie Database. 1918-10-27. Retrieved 2024-11-07. 
  2. Spoto 2016, pp. 12–15.
  3. "Teresa Wright". Hollywood Walk of Fame. 2019-10-25. Retrieved 2024-11-07.