Òturupon Meji - It Is Now A Pitiful Place

Download as docx, pdf, or txt
Download as docx, pdf, or txt
You are on page 1of 2

23/01/2022 -

(Òturupon Meji- Invocation for possession by those Ancestors who can


assist in the performance of a ritual)

Aré di aré àánú. Ìyèrè di ìyèrè arò. Bí ojú bá se méjì, won a wò'ran.

Bí esè bá se méjì, won a rìn gìrì-gìrì l'ónà. Bèbè ìdí seméjì, won a jòkó lóri eni.

Owó kan ò ró seke. Bé è ni esè kan ò se gìrì - gìrì l'ónà.

Òtòòtò ni à npe ni tí akí ì jé. Wón ní nkúnké kí nkí ará iwájú.

Mo kúnlè, mo kí ará iwájú. Wón ní nkúnlè kí npe èrò tí mbe l'éhìn.

Mo kúnlè mo pe èrò tí mbe l'éhìn. Wón ní àwon wo ni ará iwájú eni.

Mo ní egúngún ilé eni ni ará iwájú eni. Wón ní àwon wo ni èrò tí mbe léhìn.

Mo ní Òrìsà ilé Baba eni l'èrò tí mbe léhìn. Alápandèdè kó ilé rè tán,

Kò kan omi, kò kan òkè, ó gbe sí agbede méjì Òrun ó nwo Olódùmarè lójù lójù.

Ó nwo omo aráyé l'enu. Atangegere, d'Ifá fún Oyepolu lá omo Arannase,

Èyí tí Baba rè fi sílè kú ní kékeré lénje-lénje láì mo dídá owo.

Láì mo òntè ba won de Otù Ifè se odún rí.

Ó di ìgbà kíní, wón ko ohun orò sílè ó tu púrú s'ékún ó ní bí omi ni wón kó nta sílè
òun ò mo.

Ìsòrò òrun e wá bá mi tún orò yí se, ìsòrò òrun bí otí ni wón kó nta sílè'm í ò mò o.

Ìsòrò òrun e wá bá mi tún orò yí se, ìsòrò òrun bí obi ni wón ko nfi lé'le, èmi ò imò
o'. Ìsòrò òrun e wá bá mi tún orò yí se, ìsòrò òrun. Ase.

It is now a pitiful place. The chant has become a dirge.

When eyes are two, they watch events unfold.

When legs are two, they walk with heavy treading.


When the behinds are two, they sit on a mat.

One hand does not jingle. Also, one leg will not walk with a fast treading.

We are called differently. I am asked to kneel and greet those before me.

I knelt and greeted those before me. I am asked to kneel and call on those behind
me.

I knelt and called on those behind me. They ask, who are those before me?

I say one's ancestors are those before me. They ask who are those behind me?

I say it is the Òrìsà in one's family that are behind me.

When the Ethiopian swallow builds its nest.

It is suspended in the sky looking at the Creator.

Looking at humans on earth, Atangegere cast Ifa for Oyepolu child of Arannase,
whose father died when he was a child without knowledge of how to perform
divination.

And not having been to Ife for the Ifa festival.

When all the ritual materials were gathered he started crying and saying that he did
no know if water was to be offered first.

Ancestors descend and make this ritual a success for me, Ancestors tell me whether
it is gin that should be offered first, I do not know.

Ancestors descend and make this ritual a success for me, ancestors tell me whether
it is obi that should be offered first. Ancestors descend. May it be so.

You might also like